Ajimobi: A gùnlé ìdájó ilé Ẹjọ́ àkọkọ lórí ẹjọ Ajimobi - Adájọ

Gomina ana ni Ipinlẹ ọyọ Abiola Ajimọbi ti fidi rẹmi ninu ipẹjọ rẹ lati tako ibo ti o gbe ojugba rẹ Kola Balogun wọle gẹgẹ bii Sẹnatọ.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni o fagile iwe ipẹjọ ti Ajimọbi fi pe sẹnatọ naa ti o n ṣoju guusu Ipinlẹ naa lẹjọ.

Ṣe lori idibo ọjọ kẹtalelogun osu keji ọdun yii ti Balogun ni ibo 105,720 nigba ti Ajimọbi ni 92,218.

Nigba ti o n da ẹjọ naa, Justice Haruna Tsammani ni o da ipẹjọ naa nu ti o ni ko lẹsẹ n lẹ rara.

Adajọ naa ni o wa gun le igbẹjọ ile ẹjọ ti o ri si esi ibo pe idajọ ododo ni wọn ti kọkọ da.

Ile ẹjọ wa ni pe Ajimọbi ko ni aṣẹ lati sọ wi pe Balogun ko tọna lati dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.

O ni, ẹni ti ko kopa ninu eto ibo abẹle, ko ni aṣẹ lati tako ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu kọọkan.

Adajọ naa tẹsiwaju pe, kete ti ajọ ti o n ri si eto ibo ati ẹgbẹ oṣelu ba ti fọwọ si ẹnikẹni pe o kunjuuwọn, ko si idaduro mọ fun iru ẹni bẹẹ.

Tsammani wa wi pe gbogbo ẹri ti Ajimọbi ko kalẹ ko lẹsẹ n lẹ rara lati tabuku alatako rẹ.

O wa ni ile ẹjọ ṣe idajọ to yẹ nipa dida ẹjọ are fun Balogun.