You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Seyi Makinde pàṣẹ kí wọ̀n dáwọ iṣẹ́ dúró lórí iṣẹ́ àgbàṣe ₦67bn òpópónà Ibadan Lagos Bye Pass
Ijọba ipinlẹ Oyo ti paṣẹ ki awọn agbaṣẹ to n ṣiṣẹ lori opopona Ibadan Circular road eleyi ti awọn awakọ le ma gba dipo oju ọna marosẹ Lagos Ibadan lati dawọ iṣẹ duro.
Gomina Seyi Makinde lo paṣẹ yi lasiko to n ṣe abẹwọ lati mọ bi iṣẹ ti ṣe n lọ si lọna naa.
Makinde ni lati ọdun 2017 ni wọn ti buwọlu iwe adehun iṣe agbaṣe ọna naa.
Makinde ni ijọba yoo ṣe ipade pẹlu awọn kọngila ti wọn gbe iṣẹ naa fun lati le mọ ọna tawọn yoo fi wa owo iṣẹ naa tori pe opopona ohun ṣe pataki si ọrọ aje ipinlẹ Oyo.
Kilomita mẹtalelọgbọn ni ọna naa jẹ ti wọn si ya biliọnu mejilelọgọta kalẹ fun iṣẹ rẹ.
Makinde sọ fawọn oniroyin pe ida marun un le diẹ ninu ida ọgọrun un iṣẹ naa ni wọn ṣẹṣẹ ṣe.
Ọrọ owo lori iye ti wọn ya fun iṣẹ naa ti n mu ki ẹnu maa kọ awọn eeyan lori iye naa.
- Àṣírí pásìtọ̀ tó ń fí sọ́ọ̀si ṣe ọ̀gbà wèrè tú!
- Kíni àwọn ohun tó yẹ kí ẹ mọ̀ nipa àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ìjọba ìbílẹ̀?
- Kò burú bí Twitter bá fòfin dè ìpolongo òṣèlú lójú òpó - Kayode Ogundamisi
- Afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná bú gbàmù! Ẹ̀mí èèyàn 74 ṣòfò nílùú Karachi
- Zanku tó gbòde kan, wo ìtumọ̀ àti bó ṣe bá orin tuntun Zlatan mu
Awọn kan to wi tẹnu wọn loju opo Twitter sọ pe iye owo yii ti pọju lati fi ṣe opopona naa.
Gomina Seyi Makinde ko ṣẹṣẹ ma bẹnu atẹ lu iye owo agbaṣe nipinlẹ Oyo ti ijọba rẹ jogun.
Laipẹ si igba to gun ori alefa lo sọ pe agbaṣẹṣe kankan ko gbọdo mu owo ẹyin wa ba ohun bi wọn ti ṣe n ṣe pẹlu ijọba to kọja.