You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pakistan train fire: Iná ńlá ti pa ènìyàn 74
O kere tan eniyan mẹtalelaadọrin lo ti papoda lẹyin ti ọkọ reluwe to n ná ilu Karachi si Rawalpindi gbina lorilẹede Pakistan.
Minisita fun ọrọ reluwe lorilẹede naa, Sheikh Rashid Ahmed sọ wi pe afẹfẹ gaasi ti awọn eniyan fi n se ounjẹ owuro lo bu gbamu, to si fa ijamba ina naa.
Ibugbamu naa ṣe akoba fun ọkọ̀ to le ni mẹta.
Awọn osisẹ pajawiri sọ wi pe ọpọlọpọ awọn eniyan to ku naa n gbiyanju lati sa kuro ninu ina lasiko ti ijamba ọhun waye.
Wọn ni o seese ki iye awọn eniyan to ku ju bẹẹ lọ nitori eniyan ogoji lo farapa yannayanna ninu ina naa.