You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Yollywood: Yomi Fabiyi ní ìwà aṣiwèrè ni bí ọlọ́pàá ṣe ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú, táwọn òṣèré tíátà náà ń lò nínú fíímù
Ilumọọka osere tiata kan, Yomi Fabiyi ti gbarata loju opo Instagram rẹ pe, ohun ti ko dara ni bi awọn agbofinro se n tẹ ẹtọ ọmọniyan loju, eyi ti awọn osere tiata naa n gbe jade ninu ere.
Yomi Fabiyi, ẹni to se apejuwe iwa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju ti awọn agbofinro lorilẹede Naijiria n se gẹgẹ bii iwa asiwere, tun kede pe awa ọmọ Naijiria kii se ẹranko, yoo si dara ki wọn dẹkun iwa ailaju naa.
"Afihan iwa idojuti ati ailaju gbaa ni titẹ ẹtọ afurasi mọlẹ, eyi to n fa ọwọ aago idagbasoke orilẹede Niaijira sẹyin, to si tun n dena iwa alaafia pẹlu. Ẹ se idanilẹkọ ati itankalẹ iroyin yii, ki awọn ti ko mọ ẹtọ wọn lee mọ."
Fabiyi wa kesi awọn akẹẹgbẹ rẹ to jẹ osere tiata pe ki wọn ti ọwọ ọmọ wọn bọ asọ nidi sise atilẹyin ninu fiimu fun awọn agbofinro lati maa fiya jẹ awọn afurasi.
"O yẹ kẹ mọ isẹ yin bii isẹ, nitori pe awọn ọlọpaa n hu iwa yii, ko sọ pe ki awa naa se bẹẹ ninu ere tiata wa. Ere sinima kii se eremọde, oju taye fi n wo wa se pataki, ohun to tọ si lo yẹ ki awa osere maa gbe jade."
Fabiyi tun fi kun pe, awọn osere tiata lee se afihan bi awọn agbofinro se tẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ, to ba jẹ pe wọn yoo se afihan iya ti iru agbofinro naa jẹ lori iwa aidaa to hu ọhun.
Lara awọn ohun ti Fabiyi tun mẹnuba pe ko dara ninu ere, eyi to ni kawọn osere tiata yee safihan rẹ mọ ninu fiimu ree:
- Iwa nina afurasi ni anadojubolẹ titi ti onitọun yoo fi gbe ẹmi mi lasiko ti afurasi ba wa ni ahamọ awọn ọlọpaa
- Fifi wọn jẹ irora nipa tita wọn ni ibọn lẹsẹ, abi dida egbo si wọn lara lasiko ti wọn ba n fi ọrọ wa afurasi lẹnu wo
- Iwa ika awọn ọlọpaa si afurasi bii fifi irin gbigbona abi ẹrọ ilọsọ jo wọn lara
- Mimu afurasi lọna aitọ lai ni iwe asẹ to bofin mu lati mu afurasi naa ayafi ti wọn ba mu onitọun nibi to ti huwa ọdaran gangan
- Iwa ọyaju si araalu bii lilu wọn lai sẹ ẹsẹ kankan tabi gbẹsẹ le dukia wọn lọna aitọ abi gbigba owo lọwọ wọn
- Asa titẹ ẹtọ ọmọniyan loju mọlẹ ni orisirisi ọna.