BBNaija: Mercy ló gbadé BBNaija ọdún 2019

Ko si ohun to ba ni ibẹrẹ, ti kii lopin, bẹẹ lọrọ ri pẹlu eto Big Brother Nigeria to ti n waye lati bi osu mẹta sẹyin.

Lẹyin ọ rẹyin Mercy lo jawe olubori lori eto ọhun, oun lo ẹbun owo ọgọta miliọnu naira lọ ile.

Mike Edwards lo ṣe ipo lẹyin to ri ibo to pọju lọ sikeji lẹyin Mercy.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn oludije mẹrindinlọgbọn lo bẹrẹ eto BB Naija fun tọdun yii, ti wọn pe akọle rẹ ni 'Pepper Dem', ti oludije mọkanlelogun si ti ja kulẹ lasiko kan tabi omiran.

Seyi, Frodd àti Omashola dèrò ilé lórí ètò BBNaija

Ko si ohun to ba ni ibẹrẹ, ti kii lopin, bẹẹ si lọrọ ri pẹlu eto Big Brother Nigeria to ti n waye lati osu mẹta sẹyin.

Loni ọjọ Aiku si ni gbogbo eeyan yoo mọ ẹni ti yoo jaye olubori lati gba ọgọta miliọnu naira laarin awọn oludije marun to sẹkun nile BB Naija.

Bẹẹ ba gbagbe, awọn oludije mẹrindinlọgbọn lo bẹrẹ eto BB Naija fun tọdun yii, ti wọn pe akọle rẹ ni 'Pepper Dem', ti oludije mọkanlelogun si ti ja kulẹ lasikokan tabi omiran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn oludije to ku nile ni Seyi, Omashola, Mercy, Mike ati Frodd, ti anfaani si wa fun ikọọkan wọn lati moke, ti yoo si gba ẹbun owo miliọnu lọna ọgọta naira.

Koda, ọpọ awọn ololufẹ ikọọkan awọn oludije wọnyi lo ti n dibo fun ẹni ti ọkan wọn fẹ pe ko moke lori ayelujara, ti gbogbo eeyan si n foju sọna pe taa ni owo naa yoo ja mọ lọwọ.

Idahun di alẹ oni, ẹ sa maa ba wa bọ lati gbọ abọ iroyin lori ẹni to moke nile Big Brother Nigeria fun tọdun yii.