Xenophobia: Áwọn ọmọ South Africa ní kí ààrẹ Ramaphosa kọ̀ láti tọrọ aforijin lọ́wọ́ ààrẹ Buhari

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ṣọ fun aarẹ Buhari pe a ko kabamọ pe a dẹyẹ sawọn eeyan rẹ.

Esi ti pupọ awọn ọmọ ilẹ South Afrika fi dahun ikede aarẹ wọn re e nigba ti o sọ loju opo Twitter rẹ pe oun yoo gba alejo aarẹ Buhari lati Naijiria.

Lọjọ Iṣegun ni aarẹ Ramaphosa fi ikede si oju opo Twitter rẹ pe oun yoo gbalejo aarẹ Buhari to m bọ wa ṣe abẹwo ọlọjọ mẹta si ilẹ naa.

Kete ti o fi ikede yi sita ni awọn eeyan rẹ ti fesi pada lori rẹ pe:

Bi awọn ti South Afrika ti ṣe n sọ pe awọn ko fẹ ki aarẹ awọn tọrọ aforijin lawọn eeyan Naijiria kan naa n bẹnu atẹ lu aarẹ Buhari pe ko yẹ ki o gbera lọ South Afrika rara.

Wọn ni aarẹ South Afrika lo yẹ ki aarẹ Buhari fiwe pe lati wa bẹbẹ tabi ṣalaye ohun tawọn eeyan rẹ ri lọbẹ ti wọn fi waaro ọwọ si akẹgbẹ wọn nilẹ Adulawọ.

Gẹgẹ bi oun ti wọn sọ, South Afrika lo tasẹ agẹrẹ, kii ṣe Naijiria:

Iru ọrọ bayi lati ọdọ awọn eeyan orile-ede mejeeji ni awọn onwoye kan sọ pe o yẹ ki awọn olori mejeeji yi fi jọ ronu wa wọrọkọ fi sada le lori.

Bi a ko ba gbagbe pupọ awọn ọmọ Naijiria ni ijọba Naijiria fi baalu gbe pada wa sile nigba ti idunkooko awọn ọmọ South Afrika mọ wọn peleke.

Lọjọ Iṣegun ni Ileeṣẹ aarẹ orile-ede Naijiria kede pe aarẹ Muhammadu Buhari yoo ṣe abẹwo ọlọjọ mẹta si orile-ede South Afrika.

Irinajo yi gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, yoo fun aarẹ Buhari ni anfani lati ṣe ipade pẹlu aarẹ South Afrika lati le wa wọrọkọ fi ṣada nipa mimu igbe aye alaafia wa laarin awọn eeyan orile-ede mejeeji.

Aarẹ Buhari yoo ṣe ipade lasiko irinajo naa pẹlu awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Afrika lati le mọ ohun ti oju wọn n ri nilẹ naa.

Ẹwẹ, Buhari yoo dari ipade ajọ ibaṣepọ laarin Naijiria ati South Afrika nibi ti wọn yoo ti ṣe agbekalẹ iwadii ti Buhari ati aarẹ Ramaphosa yoo si buwọlu iwe adehun.