Xenophobia: South Africa bẹ Naijiria lórí ìsekúpani nítorí ẹ̀yà!

Aarẹ orilẹede South Africa, Cyril Ramophosa ti tọrọ afọriji lọwọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lori isekupani awọn ọmọ Naijiria to wa ni South Africa.

Awọn Asoju orilẹede Ilẹ South Africa lo tọrọ aforijin naa ni ilu Abuja.

Aarẹ Ramophosa naa ni ọrọ itiju gba a ni isẹlẹ naa, ti o si ran awọn asoju naa lọ si orilẹede meje ti wọn faragba ninu isẹlẹ naa.

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu igbese awọn ọmọ ilẹ South Africa to n pa awọn alawọ dudu pẹlu ẹsun pe, wọn ko jẹ ki awọn ri isẹ se.

Eniyan mejila lo ku ninu isẹlẹ naa, ti mẹwaa si jẹ ọmọ orilẹede South Africa.