Brexit: Àpẹẹrẹ́ burúkú ni ìjọba gẹ̀ẹ́sì ń fi lílẹ̀ -Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka

Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka tí ke pé àgbárijọ àwọn orilẹ̀-èdè tí o gba ominira lọ́wọ́ ìjọba gẹ̀ẹ́sì láti gbe ìjgbìmọ ti yóò lọ si ilẹ̀ gẹ̀ẹ́si láti lọ ṣe ìwádìí lóri àṣẹ̀ ti aṣòjú ìjọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́si Boris Johnson pa lọ́sẹ̀ to kọjá láti dá àwọn ilé ìgbìmọ asọfin duró lẹ́yìn iṣẹ́ wọ́n.

Ìgbésẹ̀ Boris Johnson gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣe ríi dàbi ọ̀nà láti ka àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ aṣòfin lápákò kí wan baa le dá ilẹ̀ gẹẹsì dúro láti kurò ni àgbájọ Yúróòpù lábẹ àwọn àyàfi kan ti wọ́n lè gbe sílẹ̀.

Ẹkúnrẹ́rẹ́ èróngbà ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka lóri ìgbésẹ̀ Boris Johnson

Àṣojú ìjọba ti sọ pé ààyè yóò pọ̀ fún àwọn ọmọ ilé aṣofin láti jíròrò lóri ọ̀rọ̀ náà, bótilẹ̀ jẹ pé o yé kí ilé jòkó lóri ọ̀rọ̀ náà lọjọ iṣẹ́gun.

"Mí o ti lẹ̀ mọ pé lóju ayé mi mo lé rii asoju ijóba ti yóò gbèsẹ̀ lé a[wọn ilé ìgbìmọ aṣofin láti maa pé nílẹ̀ ìgbìmọ láti ṣe iṣẹ́ tí wọ́n yàn wọ́n láti ṣe, kí ni ìtumọ èyí ṣe Oliver Cromwell ti pada dé ní"? Syinka lo sọ èyí

Soyinka fí kún pé ìjọba ilẹ̀ Gẹẹsì ń fi àpẹrẹ "ti kò dára lélẹ̀"