You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria Debt: Gbèsè Nàíjíríà yóò pòórá, tí ìkọ̀ọ̀kan ọmọ Naijiria bá san ₦121,000
Minisita feto isuna ati aato, Udoma Udo Udoma, lasiko ipade awọn ọmọ igbimọ alasẹ apapọ ni, ko si orilẹede ti kii jẹ gbese, ti aayan si n lọ lati se afikun owo ori araalu.
Bakan naa ni minisita feto ẹnawo, Zainab Ahmed kede pe gbese tilẹ Naijiria jẹ ti fo lati triliọnu mọkanlelogun ati biliọnu okoolelẹẹdẹgbẹrin ati marun naira (₦21.725trn) to wa lọdun 2017 si triliọnu mẹrinlelogun ati biliọnu lọna irinwo naira din diẹ ( ₦24.387trn) lọdun 2018.
O salaye pe gbese Naijiria lọ soke lọna ati mu ki ọrọ aje lowura, ko si tun lagbara si bi o tilẹ jẹ pe awọn araalu ko tii le foju rii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn kànga ìṣẹ̀ǹbáyé rèé ní Badagry tó ń pa ẹrú níyè
- Ìyàwò lárìnlọọ̀dù mi pè mí ní akálòlò ni mo ṣe paa - Afurasí
- "Ambode, wá jẹ́jọ́ lórí ọkọ̀ BRT 5000 to ló fi ₦45b rà, àmọ́ 820 péré ló kó wá"
- Buhari, pe ìpàdé àpérò ọmọ Nàíjíríà fún àgbékalẹ̀ òfin tuntun - Afe Babalola
- ‘Kò sí ohun tó lè yẹ ìfèhọnú ọjọ karun un Oṣu Kẹsan lórí àtìmọ́lé Omoyele Sowore’
Iwadi si fi han pe owo to to triliọnu meji ati biliọnu lọna ogoje naira (₦2.14trn) ni ijọba n na lati san ele lori awọn gbese naa lọwọ-lọwọ.
Amọ laipẹ yii ni ijọba apapọ kede pe ko sewu loko afi giri aparo nipa gbese ti orilẹede wa Naijiria jẹ silẹ okeere.
Eyi si lo mu ki oju opo ayelujara maa gbona lori bi awọn ọmọ Naijiria se n gbarata, lori bi gbese tilẹ wa jẹ se n fi ojoojums fo lọ soke.
Koda awọn eeyan kan tiẹ se alaye pe, niwọn igba ti a mọ iye eeyan to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria, ti wọn jẹ miliọnu lọna igba eeyan, ti gbese wa si jẹ triliọnu mẹrinlelogun ati biliọnu lọna irinwo naira din diẹ ( ₦24.387trn).
Wọn ni ta ba pin iye gbese yii le ori ọmọ Naijiria kọọkan, a jẹ pe gbese okoolerugba ati ẹyọ kan naira (₦121,000) lo wa lori ọmọ Naijiria kọọkan ti yoo san.
Lero tawọn eeyan yii, wọn ni owo yii ko pọ rara fun ikọọkan ọmọ Naijiria lati san, ka lee fagile gbese ti ilẹ wa jẹ, ka si wa lai ni gbese lọrun, eyi ti yoo fun wa ni anfaani ọtun lati mu ki ọrọ aje wa ru gọgọ si.
Eyi lo wa mu ka maa beere pe, se ẹ setan lati san gbese tiyin tii se ₦121,000?