You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn ọmọ Yorùbá wo ni mínísítà ní ìjọba Buhari?
Aarẹ Buhari ti bura fawọn minisita tuntun loni
Bakan naa lo ya ileeṣẹ ijọba ti wọn yoo mojuto fun wọn.
Meje ninu awọn minisita naa ni wọn yan lati ẹkun iwọ oorun gusi orilẹede Naijiria.
Awọn meje naa niyi ati itan diẹ nipa wọn.
Babatunde Faṣọla SAN
Ni ọjọ kejidinlọgbọn ọdun 1963 ni wọn bi Babatunde Raji Faṣọla ni ilu Eko.
O lọ si ileewe Birch Freeman High school Lagos ati Igbobi College ni ilu Eko ki o to gba fasiti Benin lọ lati kawe gba imọ ijinlẹ ninu ẹkọ ofin lọdun 1987.
Faṣọla ni olori awọn oṣiṣẹ labẹ gomina ipinlẹ Eko lasiko to fi n ṣe akoso ijọba ipinlẹ Eko.
Ni ọdun 2007 ni Faṣọla di gomina ipinlẹ Eko.
Ipa ribiribi to ko pẹu iṣejọba rẹ ninu idagbasoke ipinlẹ Eko kun ara ohun ti o mu ki ọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria fẹran rẹ.
Faṣọla kun ara awọn minisita ti ọpọ n wo gẹgẹ bii alagbara ni saa iṣejọba akọkọ aarẹ Buhari, paapaa julọ bi o ṣe jẹ pe ohun nikan lo di ileeṣẹ ijọba mẹta to ṣe koko mu.
Ni saa keji yii ẹru ọrun rẹ ti rọrun diẹ nitori aarẹ Buhari ti yọ ileeṣẹ kan kuro ni ileeṣẹ mẹta ti o n mojuto tẹlẹ.
Rauf Arẹgbẹṣọla
Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla, ní a bí ni ọjọ́ karundinlọgbọn, oṣù Kàrún un, ọdún 1957.Ó ṣe kọmiṣọna fún eto ìṣẹ ode ni Ipinle Èkó ni ọdun 2009.
Bákan náà, ní ọdún 2010, ó gbé àpótí ibo láti dije fún gomina ipinle Osun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
Bo tilè jẹ pe, ilé ẹjọ́ lo gbaa fún un, Rauf Aregbesola, di gomina ipinle Osun ni odun 2010 sì ọdún 2018.Ní báyìí, Aare Muhammadu Buhari só ọ di minisita fún ọrọ abele lorile-èdè Nàìjíríà.
Otunba Nìyí Adebayo
Ọtunba Nìyí Adebayọ ni a bí ní ìlú ìyìn Ekiti ni ọjọ́ kẹrin, oṣù kejì, ọdún 1954.Nìyí Adebayo ni Gomina alágbáda àkọ́kọ́ ní ìpínlè Ekiti laarin ọdun 1999 sì ọdún 2003 ni abẹ ẹgbẹ oselu AD.Ní báyìí, Ó jé ọkàn pàtàkì lára àwọn àgbààgbà egbe oselu APC ni orílè-èdè yìí.Ó jé amofin nípa eto epo àti gaasi. Ó feran boolu alafesegba. Ó sì jẹ ọmọ ẹgbẹ́ àwọn asofin ni ile wa Naijiria ati ni òkè òkun.
Sẹnetọ Ọlọrunnibẹ Mamoora
Abii ni ọjọ kẹrindinlogun, osu keji, odun 1953 ni ipinlẹ Eko. Ó kẹkọọ gboyè nínú ìmọ̀ ìlera, ni ile iwe olododo Fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, Ile Ifẹ, nibi ti o si tún ti kẹkọọ siwaju síi ni nipa iṣẹ abẹ siṣe.O jawe bori nínú idibo ti ọdun 1999, èyí tí ó gbé e wo ilẹ̀ ìgbìmò asofin ipinle, Eko nibi ti o ti jẹ agbẹnusọ fún ile naa.Lẹyin naa o tún jawe olú borí nínú idibo tí ó gbé e wo ilẹ̀ igbimọ asofin àgbà n'ilu Abuja ni odun 2003.O tún tesiwaju sì ilé ìgbìmò asofin àgbà lé èkejì ni odun 2007.
Olamilekan Adegbitẹ
O jé kòmisona fun eto ìṣe àti ohun amayederun tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlè Ogun. Ó kẹkoọ jáde nípa eto oro àyíká ni Fáṣítì ìjọba apapo tí ìlú Èkó. O ṣi tún kẹkọo síwájú sii nípa ìmò ilé kíkó ni Fáṣítì kan náà.