You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun: Ìjọba kédeìsinmi fáwọn òṣìṣẹ́ láti ṣe àjọ̀dún àyájọ́ ọdún Ìṣẹ̀ṣe
Gbogbo wa la mọ pe gbogbo ọdun Kiristẹni ati musulumi lorilẹede yii ni ijọba apapọ maa n kede isinmi lẹnu iṣẹ fun.
Ọpọ ọmọ orilẹede yii, paapaa julọ awọn ti wọn fi si idi iṣẹse ẹya kọọkan ni wọn ti n fi ẹhonu han lori ohun ti o n faa gan an ti ijọba kii fi kede isinmi lẹnu iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ lasiko awọn ọdun iṣẹse.
- Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu Mercy Aigbe lórí bó ṣe ki Adeniyi Johnson
- Òyìnbó sísọ di èèwọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ekiti
- Yàtọ̀ sí Ọ̀ṣun Òṣogbo, Ṣàǹgó pẹ̀lú a máa ní arugbá lóde Ọ̀yọ̀
- Falana àtàwọn míì péjú síbi àpérò #RevolutionNow l'Eko
- SSANU, NASU gbé fásitì Ibadan tì pa
- Ayédèrú Ọ̀ṣun ni wọ́n ń bọ lónìí, kìí ṣe ojúlówó - Bàbá Ọlọ́ṣun tún figbe ta
Nibayii, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti gbe igbesẹ akọ lori rẹ.
Ijsba ipinlẹ Ọṣun ti kede ọjọ iṣẹgun tii ṣe ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun 2019 gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ.
Kii ṣe ori iṣejọba gomina Gboyega Oyetọla ni igbesẹ yii ti bẹrẹ bikoṣe lati ori Rauf Arẹgbẹṣọla to ṣiwaju rẹ.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọrs abẹle fi sita, ijọba ipinlẹ Ọṣun rọ awọn ẹlẹsin iṣẹṣe lati ṣe ọdun wọn naa ni pẹlẹ-putu ki wọn si ṣe iwure fun ijọba ki ohun gbogbo lee lọ nirọwọ rọsẹ, ki eku lee ke bi eku, ki ẹyẹ si maa ke bi ẹyẹ.