You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹgbẹ́ Akọ́mọlédè: A kan sáárá sí ìpínlẹ̀ Eko fún sísọ èdè Yorùbá di dandan nílé ẹ̀kọ́
Aarẹ ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa, Arabinrin Ọmọwumi Falẹyẹ ti parọwa si awọn ijọba ipinlẹ to wa nilẹ Kaarọ Oojiire, lati tẹwọgba ede Yoruba, ki wọn si maa se agbega rẹ nigba gbogbo.
Aya Falẹyẹ rawọ ẹbẹ yii ninu ọrọ ikinni kaabọ rẹ nibi ayẹyẹ iside ipade apero ọlọdọọdun ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa Yoruba, eyi ti wọn tun fi n sami aadọta ọdun ti wọn da ẹgbẹ naa silẹ, to waye nilu Kabba, nipinlẹ Kogi.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọlọ́pàá yọ ìbọn sí mí pé kí n tọwọ́ bọ ìwé ní tipá - Busola Dakolo
- Ọmọ Yorùbá míràn tún dé ipò gíga l‘Amẹrika
- "Mo fẹ́ pa ara mi torí ojú àbùkù tí wọn ń fi wò mí pé mo fi iṣẹ́ abẹ bímọ"
- Owó dé! Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ òfin kọ̀ọ̀kan yóò gba ₦500,000 owó ìrànwọ́ l‘Oyo
- Fulani kò leè dúró, táa bá lo ohun ta jogún lọ́dọ̀ àwọn bàbá wa - Sunday Igboho
Aarẹ ẹgbẹ Akọmọlede, ẹni to mọ riri awọn ijọba ipinlẹ to sọ ede Yoruba sisọ ati kika lawọn ileewe di kanpa, tun mọọmọ gbe osuba fun ijọba ipinlẹ Eko fun igbesẹ naa, to si rọ awọn ipinlẹ yoku ti ko ba tii se bẹẹ lati fi ipinlẹ Eko ṣe awokọṣe rere.
"Mo n rọ awọn ijọba to n dari awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba lati sọ ede Yoruba sisọ ati kika di kanpa lawọn ileẹkọ alakọbẹrẹ ati girama ni ipinlẹ koowa wọn, ki gbogbo wa si pawọpọ maa polongo agbega ede Yoruba kari aye."
Bakan naa lo tun rọ awọn obi lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn olukọ, nipa sise afihan ifẹ wọn si ede abinibi, aṣa ati iṣe ilẹ Kaarọ Oojire lasiko ti awọn ọmọ wọn ba wa nile tabi nile ẹkọ laisi ifiyajẹni.
Nigba to n mẹnuba awọn iṣoro to n ba ẹgbẹ Akọmọlede ati Aṣa Yoruba finra, aarẹ ẹgbẹ naa beere fun atilẹyin awọn ẹlẹyinju aanu, oninu rere, awọn eeyan ti Ọlọrun bẹ igi ọla fun lawujọ ati awọn ileeṣẹ nlanla, lati wa yọ ẹgbẹ naa ni ọfin awọn iṣoro to jin si, nipa aini irinṣẹ to pegede.
Ẹgbẹ Akọmọlede wa dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Kogi fun bo se gba ẹgbẹ naa lalejo, fun ayẹyẹ aadọta ọdun wọn, ti wọn si gbadura pe iwaju ni ọpa ẹbiti ipinlẹ naa yoo maa re si.
Lara awọn eto pataki to waye lasiko ajọdun aadọta ẹgbẹ naa ni gige akara oyinbo, ọdun Ogun bibọ, abẹwo si awọn ibudo manigbagbe ati fifun awọ̀n eeyan jankan jankan lami ẹyẹ.