Police Ondo: Láìpẹ́ ni ọwọ́ yóò tẹ àwọn agbébọn tó wa òṣìṣẹ́ wa

Awọn gende agbebọn ti yinbọn pa osisẹ ọlọpa kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Lasisis lasiko to wa loju popo se ayẹwo ọkọ lopopona Isua-Ise-Akoko nipinlẹ Ondo.

Awọn agbebọn ọhun, ti ko si ẹnikẹni to mọ idamọ wọn, lo sadede bẹ jade lati inu igbo to wa lẹba opopona naa, ti wọn si n yinbọn mọ awọn ọlọpa naa, ti wọn wa lati agọ ọlọpa Isua.

Nigba to n fi idi isẹlẹ naa mulẹ, osisẹ alarina fun ileesẹ ọlọpa ipinlẹ Ondo, Fẹmi Joseph salaye pe awọn osisẹ ọlọpa ti n finmu finlẹ lati se awari awọn olubi ẹda to sisẹ laabi ọhun.

"A ti n sisẹ kara lati mọ awọn eeyan naa, laipẹ laijinna si ni ọwọ wa yoo tẹ wọn ninu igbo ti wọn sa lọ."

Joseph salaye pe, o ti le ọdun kan ti awọn ọlọpa naa ti wa loju popo lati pese eto aabo si agbegbe naa, amọ o se ni laanu pe awọn olubi ẹda naa tun lori laya lati wa kọlu awọn ọlọpa gan.