You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Revolution protest: Àjọ DSS ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbé Sowore
Ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS ti fidi rẹ mulẹ pe lootọ, oun l'oun mu oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu African Action Congress, Omoyele Sowore si ahamọ.
Ọgbẹni Sowore, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters, jẹ ọkan lara awọn to ṣe agbatẹru iwọde kan ti ẹgbẹ Global Coalition for Security and Democracy in Nigeria, fẹ ẹ ṣe ni ọjọ Aje, ọjọ karun un oṣu Kẹjọ ọdun 2019 ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe "ete iditẹ gba ijọba ni iwọde naa."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Dangote, jọ̀ọ́ nawọ́ ìrànwọ́ láti dá iléeṣé sílẹ̀ fún wa ní Ọyọ - Aláàfin rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Ọlọkọ tó ṣàfihàn ìhòòhò obìnrin ní Lekki n fí ẹwọn ọdún mẹ́ta runmú- Ìjọba Èkó
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
- Ìjọba Buhari ń wùwà bíi ìjọba Abacha lórí ọ̀rọ̀ Ṣoworẹ- Ṣoyinka
Agbẹnusọ fun ajọ DSS, Peter Afunaya sọ fun BBC pe, awọn lọ ọ gbe oludasilẹ iwọde naa, ti wọn pe 'Revolution Now' ni owurọ ajọ Abamẹta to kọja, nitori pe oun n pe fun iditẹ gba ijọba.
Ṣaaju ọjọ naa ni ikọ Coalition for Revolution ti Sowore da silẹ, ke si awọn ọmọ Naijiria kaakiri orilẹede yii lati jade si igboro, ki wọn si beere fun opin si aisi aabo ni Naijiria.
Ẹgbẹ naa tun n beere fun ẹkọ ọfẹẹ, ati eto ilera fun gbogbo eniyan, ati eto ọrọ aje to dara.
Amọ ajọ DSS ko sọ boya wọn yoo mu ẹnikẹni to ba yọju fun iwọde naa l'ọjọ Aje.
Awọn ileeṣẹ iroyin kan sọ pe, agbẹnusọ ajọ DSS, Afunaya sọ pe awọn gbe igbesẹ naa ni ibamu pẹlu ojuṣe wọn l'abẹ ofin.