You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Lórí ọ̀rọ̀ Pásítọ̀ COZA àti Dakolo, Ìwadìí ń tẹ̀ síwájú, ṣùgbọ́n a kò mọ ohunkohun nípa rẹ̀ mọ́- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Èkó
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni awọn ko mọ ohunkohun mọ nipa ẹjọ ẹsun ifipabanilopo ti iyawo gbajugbaja olorin Timi Dakolo, Busọla, pe tako Pasitọ Fatoyinbo.
Gẹgẹ bii alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Bala Elkana ṣe sọ fun BBC News Yoruba, wọn ti ko iwe ẹjọ naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria, nilu Abuja nibi ti iwadii naa ti n tẹ siwaju.
Amọṣa nigba ti a pe alukoro apapọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede Naijiria lori ẹrọ ibanisọrọ, a ko rii ba sọrọ.
Ni opin ọsẹ to kọja ni Timi Dakolo ke ibosi sita pe lẹyin ọpọlọpọ ọsẹ ti awọn ti fi iwe ipẹjọ siwaju ileeṣẹ ọlọpaa, awọn ko tii gbọ pe wọn ti pe iranṣẹ Ọlọrun naa fun ifọrọwanilẹnuwo.