You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
RUGA: Gbogbo ọmọ Nàìjíríà ló lásẹ láti gbé ìlú tó bá wù ú - Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ke si awọn Fulani darandaran ni Guusu iwọ Naijiria lati da asẹ ẹgbẹ Northern Elders Forum (NEF) nu to ni ki wọn pada wa si oke ọya ni kiakia.
Oluranlọwọ pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari, Garba Shehu lo fi ọrọ yii lede ninu atẹjade ti aarẹ fi sita.
Ninu atẹjade naa, Aarẹ Buhari ni gbogbo ọmọ Naijiria lo ni anfaani ati eto lati rin kaakiri agbeegbe ti o ba wu wọn, tabi ki wọn gbe nibẹ.
Aarẹ Buhari ni iwe ofin orilẹede Naijiria, ijọba Naijiria ati isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari yoo da abo bo awọn ọmọ Naijiria ni ibikibi ti wọn ba wa.
Laipẹ yii ni Ajọ Northern Elders Forum (NEF) ke si awọn darandaran Fulani kí wọ́n padà sókè ọya ní kíákíá pé ẹmi wọn ati dukia lee wa lewu ni iha Guusu ti wọn wa.