You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Diezani Madueke: Díẹ̀ lára ohun ìni Diezani tí ilé ẹjọ́ gbẹ́sẹ̀ lé
Ile ẹjọ ti ni ki awọn ẹṣọ ara kan, ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ iphone oni goolu kan to jẹ ti Minisita nigba kan ri fun ọrọ epo rọbi, Diezani Alison-Madueke di igbagbe.
Gbogbo dukia ọhun ti apapọ owo wọn jẹ ogoji miliọnu dọla ni Onidajọ Nicholas Oweibo, ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Ikoyi nipinlẹ Eko sọ pe ko di ti ijọba.
Ọjọbọ ni Onidajọ Oweibo gbe idajọ naa kalẹ lẹyin ti ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC kọ iwe ẹbẹ kan pe ki ile ẹjọ o ṣe bẹ ki igbẹjọ ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan Madueke o to maa tẹsiwaju.
Ajọ EFCC, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Rotimi Oyedepo, ṣalaye fun ile ẹjọ pe inu ile Madueke ni wọn ti ko awọn nkan iṣaraloge ọhun.
EFCC sọ pe ara fu oun pe owo ti olujẹjọ ko jọ lọna aitọ lo fi ra wọn.
Ninu idajọ rẹ, Onidajọ Oweibo paṣẹ pe ki EFCC kede gbigbẹsẹ le awọn dukia naa ninu gbaju-gbaja iwe iroyin kan laarin ọjọ mẹrinla, lati fun olujẹjọ tabi ẹlomii to ba nifẹ ninu wọn ni anfaani lati sọ idi ti ijọba ko fi gbọdọ gbẹsẹ le wọn titi lai.
Diẹ lara awọn ẹṣọ ara ọhun ni ẹgbà ọwọ (419); oruka ọwọ (315); yẹti (304); ẹgba ọrun (267); aago ọwọ (189); ẹgba ọrun ati yẹti alaṣepọ (174).