Osun : Ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ fi òǹtẹ̀ jan Oyetola gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà Osun

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ ní ìlú Abuja ti dá Gboyega Oyetola láre gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà Osun.

Ninu idajọ to fi sita nilu Abuja laarin Gomina Gboyega Oyetola ati Sẹnetọ Ademọla Adeleke,Adajọ Bode Rhodes-Vivour fọwọ rọ ẹjọ ti Adeleke gbe wa lati tako idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Adajọ naa ni tori eleyi, Gomina Oyetola ni ile ẹjọ fi ontẹ jan gẹgẹ bii Gomina.

Kete ti iroyin idajọ yi kan awọn ololufẹ Gomina Oyetola nilu Oṣogbo ni wọn tuyaya sita lati da ọwọ idunu

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Loju opo Twitter ẹgbẹ oṣelu APC,awọn naa ti ki Gomina Oyetola ku orire aṣeyọri rẹ nile ẹjọ

Paro paro ni ile Adeleke da ni Ẹdẹ

Akọroyin wa to ṣe abẹwo si ilu Ẹdẹ la ti mọ bi awọn ara ilu naa ti ṣe gba iroyin ohun jabọ pe paroparo ni ita ile Ademola Adeleke da.

O sọ pe awọn to wa ni ibẹ tilẹ sọ pe Adeleke ko si ni ile rara.