You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
RUGA: Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan ní kí Buhari máà fi ọ̀rọ̀ RUGA kọ́ òun lọ́rùn
Emi ko mọ nipa Ruga o - Goodluck Jonathan
Aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti kọminu lori ọrọ kan ti gomina ipinlẹ Plateau sọ pe lasiko iṣejọba Jonathan ni wọn ti ṣeto itẹdo darandaran RUGA silẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria.
Jonathan ṣalaye pe iṣejọba oun ko figba kankan ṣe ohun to jọ bẹẹ ati pe eto ẹyawo da ibujẹko maaluu silẹ RANCHES ni oun gba lero.
Eyi si yatọ patapata si agbekalẹ gaa Fulani ti Ruga ti ijọba Buhari n gbero yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ninu atẹjade kan eyi ti ọkan ninu awọn agbẹnusọ rẹ, Reno Omokri, fi sita, Aarẹ Goodluck Jonathan ni ko si igba kan ti iṣejọba oun ya biliọnu mẹwaa naira (N10 billion) sọtọ fun idasilẹ itẹdo darandaran RUGA.
Jonathan ni o to asiko ki aarẹ Buhari atawọn ẹmẹwaa rẹ yee da ẹbi awọn ijakulẹ wọn ru elomiran ki wọn si mojuto ipenija gbogbo 'ti wọn fi ọwọ ara wọn fa'
"Itẹdo darandaran RUGA ti ijọba n gbero rẹ bayii kii ṣe atọwọda iṣejọba Jonathan.
A ko gbe iṣuna kalẹ fun un, a ko si ni ohunkohun un ṣe pẹlu rẹ.
"Ohun ti ijọba Jonathan ṣe ni lila eto owooya sọgbin ọlọgọrun un bilọnu naira (N100billion) kalẹ fun banki apapọ.
A ṣee lati ya awọn ipinlẹ lẹkun oke ọya Naijiria ti wọn nifẹ ati kọ oko ijẹko maluu fun pipese ẹran maluu lọna igbalode eyi ti wọn yoo maa gbe ninu rẹ dipo dida ẹran maluu kaakiri."
Jonathan ni RUGA ti ijọba Buhari gbe kalẹ kii ṣe ẹyawo bikoṣe eto ijọba lati na owo ilu lati fi gbe okoowo aladani larugẹ pẹlu gbigba ilẹ ilu fun awọn okoowo adani bẹẹ.
Jonathan gba ijọba Buhari ni imọran lati tẹti si ohun ti awọn ara ilu n fẹ.