You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Election Tribunal: INEC ní òfin kò ní kí èsì ìbò ààrẹ wà lórí ''server''
Ala ti ko lee ṣẹ ni ''server'' ti oludije ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar n beere fun.
Atiku n beere esi idibo ibo aarẹ orilẹ-ede Naijiria to waye ninu oṣu keji, ọdun 2019.
Kọmiṣọna ajọ eleto idibo INEC, Festus Okoye lo ṣalaye ọrọ naa nigba to ba BBC sọrọ lọjọ Ẹti.
Ọgbẹni Okoye sọ pe esi ibo aarẹ ko si ninu ''server'' INEC tabi ẹrọ kọmputa nibi kankan.
O ṣalaye pe ofin eto idibo lorilẹ-ede Naijiria ko sọ pe ki ajọ INEC ko esi idibo aarẹ sinu ''server'' kọmputa INEC.
Okoye ni ọwọ ni wọn fi kọ esi ibo ni gbogbo ibudo idibo kaakiri orilẹ-ede Naijiria, eleyi ti gbogbo awọn aṣoju ẹgbẹ osẹlu to wa nibẹ foju ri ti wọn si ni ẹda rẹ.
O sọ pe awọn esi ibo yii ni wọn fi ṣọwọ si ajọ INEC lawọn ipinlẹ to fi de olu ile iṣẹ INEC nilu Abuja.
Ẹwẹ, l'Ọjọbọ ni ajọ INEC ṣi aṣọ loju ọrọ yii nigba to sọ fun igbimọ igbẹjọ ibo aarẹ l'Abuja pe oun ko ni ''server'' ti Atiku ati PDP n beere fun.