You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Gov Ganduje Vs Sanusi: Ganduje kò lẹ́tọ̀ọ́ láti yan Emir mẹ́rin
Ile ẹjọ giga to kalẹ si ipinlẹ Kano ti ni otubantẹ ni igbesẹ Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje pẹlu bo se yan Emir mẹrin miran ni ilu Kano.
Ile ẹjọ naa pasẹ fun gomina naa lati da gbogbo nkan pada si bose wa tẹlẹ ki igbẹjọ fi le waye lori igbesẹ gomina to yan Emir tuntun.
Iwe igbẹjọ naa fẹsun kan gomina Ganduje pe ikunsinu lo mu ki o gbe igbesẹ naa lati din agbara Emir Lamido Sanusi ku gẹgẹ bi Emir ilu Kano.
Opin ọsẹ to kọja ni Gomina Ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje fi iwe asẹ fun awọn Emir tuntun mẹrin lati bẹrẹ isẹ.