You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olórin tàkasúfèé pàdánù mílíọ̀nú náìrà kan lori ìfẹsẹ̀wọsẹ̀ Liverpool Vs Barcelona
Olorin takasufẹ ọmọ orileede Naijiria kan ti farakasa miliọnu Naira kan lori ifẹsẹwọnsẹ Champions League to waye laarin ẹgbẹ Liverpool ati Barcelona.
Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa Liverpool ja ireti Barcelona kulẹ pẹlu ami ayo mẹrin si mẹta.
Gẹgẹ bi ohun ti a ri ka loju opo Twitter niṣe ni Gbajugbaja olorin takasufe ni, Kcee leri si Dike Chidozie@mrchidozie pe oun yoo fun ni miliọnu naira kna ti Liverpool ba fi le na Barcelona.
Wakati kan abọ lẹyin ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ọrọ ni iyanju ti Liverpool si pegede ti Kcee si padanu miliọnu Naira kan.
Kcee wuwa ọmọluabi ti o si ṣika adehun rẹ si Chidozie.
O san owo si akoto Chidozie ti oun naa si fi idupe sita loju opo Twitter pe oun ti ri ''alert'' gba