You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Davido, Simi,Omawumi gbégba orókè nínú ìdíje 2018
Àwọn ọmọ tó jáwé olúborí ní 'Headies' 2018
Ọ̀kẹ́ àìmọye olórin lo kópa níbi igbami ẹyẹ headies elekeejila tí ọdún 2018.Ṣùgbọ́n Simisola Bolatito Ogunleye (Simi), David Adedeji Adeleke (Davido) àti Omawumi Megbele (Omawumi) lọ gbegba oroke níbi ayẹyẹ náà. Láti ọdún 2006 ni 'Headies' tí ń fáwọn to bá pegede nínú ìṣe orin takasufe lami ẹyẹ lorile-ede Naijiria.
Simi gba àmì ẹyẹ to dára ju lọ nínú RnB nínú orin adako rẹ 'Smile For Me' 'Joromi' bákan naa lọ gba Aliboomu tí dára julọ. Davido gba àmì ẹyẹ olórin to gbayii julọ àti orin to gbayii.
Nígbà tí Omawumi gbá àmì ẹyẹ obìnrin tó ní ohun tó dùn julọ ninu orin rẹ 'Butterfly'.