You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
NUT ní àìsí àbò ń ṣàkóbá fún àwọn olùkọ́ ní Nàìjíríà
Ko din ni ẹgbẹta olukọ ti wahala aabo to mẹhẹ ni apa ila oorun ariwa orilẹede Naijiria ti ran lọ sọrun ọsan gangan.
Ẹgbẹ awọn olukọ lorilẹede Naijiria lo tu aṣiri eyi sita to si ṣakawe eyi gẹgẹ bii ohun to buru jai to si bani ninu jẹ lọpọlọpọ.
Akọwe agba ẹgbẹ NUT lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Mike Ike-Ene ṣalaye fawọn oniroyin pe ọpọ igba lo jẹ pe awọn olukọ nii fi ara ko ina wahala igbesunmọmi tabi rogbodiyan lasiko to ba ṣẹlẹ lawọn agbegbe oke ọya orilẹede Naijiria.
O fi kun un pe, ni ikọlu awọn agbebọn to waye ni ileewe girama awọn obinrin ni ilu Moriki, nijọba ibilẹ Zurmi, ipinlẹ Zamfara, awọn alase meji atawọn akẹkọ mẹrin ni awọn agbebọn naa ji gbe salọ.
O ni ohun to n ṣẹlẹ yii n bu omi tutu si ọkan awọn olukọ to n ṣiṣẹ ni ẹkun naa ti kii sii fẹ jẹ ki ọpọ olukọ o faramọ ki iṣẹ gbe wọn lọ sibẹ pẹlu.