Akanbi Oluwasegun: Mo yá owó ni kí ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ adìyẹ yìí tó di odidi

Àkọlé fídíò, Ọ̀dọ́kùnrin tó kọ́kọ́ ṣe ẹ̀rọ tó ń tu ìyẹ́ lára adìyẹ

Ìrọ̀rùn dé! Fun àwọn tó mọ rírì iṣẹ ti ẹrọ lee ṣe lati din wahala akoko gbọọrọ ku lori iṣ kan.

Lẹyin ti Akanbi Oluwasegun pari ile iwe ati ẹkọsẹ, o ti ṣiṣẹ kaakiri plu awn eniyan o si ti rii wi pe ko sohun to da bii iṣ ara ẹni.

Eyi lo mu ki Akanbi gbe igba owo pipa adiyẹ ta. Pẹlu eyi, o si tun boju wo ọ̀na tiṣẹ rẹ le fi yatọ si awọn mii to n pa adiyẹ ta bii tirẹ.

Bi ẹrọ to lee tu iyẹ lara adiyẹ ṣe wa de'lẹ latọwọ Akanbi, aramanda ni.

Iṣẹ ọpọlọ yii da yatọ gedegbe, a lee ni lagbegbe ti arakunrin yii wa, ko tii si ẹni to ṣe iru eleyii ri. A o le sọ lagbaye o.