Cholera Vaccine: NAFDAC kìlọ̀ lórí ayédèrú òògùn ààrùn onígbáméjì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ to n mojuto aṣilo oogun ati ounjẹ, NAFDAC ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria pe ayederu oogun aarun onigbameji ti ọpọ mọ si Kọlẹra ti gbode kan bayii lorilẹ-ede Bangladesh.

Ọga ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Moji Adeyẹye ṣalaye pe ede oyinbo ati Faranse lo wa lara oogun ọhun ti orukọ n jẹ Dukoral.

Ọjọgbọn Adeyẹye fikun ọrọ rẹ pe ajọ to n ri si ọrọ ilera lagbaaye, WHO ti ko bi ẹgbẹrun lọna mẹjọ paali ayederu oogun ọhun nilẹ.

O ṣapejuwe bi paali ti oogun naa ninu rẹ bayii: 1. Orukọ oogun naa- Dukoral Oral Cholera Vaccine/ Vaccin Oral contre le Cholera

2. Nọmba paali rẹ- KV8262B1

3. Ọjọ ti yoo bajẹ- 2020-04

4. Ile iṣẹ to ṣe e- Valneva Canada Inc.

Ọga ajọ NAFDAC ṣalaye pe ile iṣẹ to ṣe ojulowo oogun aarun onigbameji naa ni Valneva Sweden AB, ti awọn eeyan mọ si Crucell Sweden AB tẹlẹ.

O fikun un pe ajọ NAFDAC ko fi ontẹ lu oogun kọlẹra Dukoral lorilẹ-ede Naijiria.

Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati ko ayederu oogun kọlẹra ti wọn ba ri lọ si ile iṣẹ ajọ NAFDAC to ba wa ni tosi.