Lagos Beach: Àwòrán tó làmììlaaka nípa àwọn òsìsẹ́ ẹ̀ṣọ́ etí òkún

Ile igbafẹ eti okun sẹsẹ bere isẹ ni ilu Eko ni. Amọ oun to dun mọ ni ninu ni wi pe ile igbafẹ yii ni awọn asọle ti yoo ma sọ awọn eniyan to n wẹ ni eti odo.

Ọkan lara awọn osisẹ ibi igbafẹ yii, Stephen Boboly ni oun ti gba ẹmi ọpọ eniyan la ninu okun lati bii ọsẹ mẹta bayii.

"Idunnu mi ni wi pe a n gba awọn eniyan la, ki wọn ma ba a ku sinu omi. inu mi dun nitori pe wọn ma n padawa lati wa dupe." O sọfun BBC bẹẹ.

Arakunrin ẹni ọdun aadọta naa wa lati idile awọn apẹẹja,nitori naa ni awọn eniyan se bọwọ fun gẹgẹ bi omuwẹ ni ipinlẹ Eko.

Ọpọlọpọ odo igbafẹ lo pọ ni Eko, amọ eleyii to wa ni agbẹẹgbẹ Victoria Island yii ma n gba ẹgbẹwa Naira, 2,000 Naira ($5.50; £4) .

Ọkan lara awọn ẹsọ eti okun yii ma n wa ni ibi isẹ laarin ọsẹ, nigbati mẹta si n sisẹ ni opin ọsẹ ti awọn eniyan ma n pọ ni eti okun.

Lẹyin ọsẹ mẹta ti arakunrin Boboly gba isẹ, a ma a lo pa ẹja laarin aago kan si aago mẹta ki o le ri owo fi ransẹ si ile.

Akẹẹgbẹ rẹ Nicholas Paul naa kọkọ bẹrẹ gẹgẹ bi apẹẹja, ko to di wi pe o beere isẹ ẹso eti okun lati bi ọdun meje sẹyin.

Ohun ti o mu ẹni ọgọta ọdun naa di ẹsọ ẹti okun ni wi pe, ti o ba lọ pa ẹja lodo, wọn ma n ri oku awọn eniyan ti yoo wa si eti okun. Eleyii lo mu ki oun fi ara rẹ jin fun isẹ sisọ ẹti okun.

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ awọn ẹsọ ẹti ọkun, ibi ti wọn ti ma n ri owo ni awọn ti wọn ma n fun wọn lọwọ lẹyin ti wọn ba gba wọn la lọwọ iku.

"Awọn ọmọ Naijiria ko mo o wẹ, amọ ti o ba sọ fun wọn, wọn ko ni gbo, won a ma a ba ẹ jiyan " O salaye.

Apẹẹja tẹlẹri yii ni o ri isẹ lẹyin to o gba awọn oluwẹ mẹta lati ilẹ Indian la. O ni ohun to dara ni ti awọn omuwẹ ba ni awọn ohun igbalode to dara.

Samuel Omohon to jẹ omuwẹ naa kọ lati maa wẹ ni sapẹlẹ ninu omi nla Niger Delta nigba to n dagba.

Ọgbẹni Omohon ni aworan gbogbo awọn to ti gbala lati ọdun bọdun ati igba ti o lugbadi omi gbigbona, nigba ti epo gbigbona jọ ọwọ rẹ, amọ ti ko si di i lọwọ isẹ.

BBC's Grace Ekpu lo ya awọn aworan yii