Osun Tribunal Judgement: 'Àwa ènìyàn Ọṣun kọ ìdájọ́ tó ní Oyetọla kọ́ ló wọlé sípò gómìnà'

Awọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, Adejare Taofeek

Kẹtikẹti ni awọn olugbe ipinlẹ Ọṣun tu sita lọjọru lati ṣe iwọde tako idajọ igbimọ to sọ pe Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party lo jawe olubori ninu idibo sipo gomina ipinlẹ naa to waye lọdun 2018.

Awọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, Adejare Taofeek

Àkọlé àwòrán, 'Awọn eniyan ipinlẹ Ọṣun kọ idajọ Jankara

Nibi iwọde naa to waye nilu Oṣogbo ni awọn to wọde ti gbe oriṣiriṣi akọle dani lati fi sọ erongba wọn.

Àkọlé fídíò, Adeleke: Àwọn ará Ẹdẹ bẹ síta pẹ̀lú ìdùnnú lórí ìdájọ́ èsì ìdìbò gómínà Ọṣun
Awọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, Adejare Taofeek

Àkọlé àwòrán, 'Oyetọla ni Ọṣun dibo fun.'

Ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun oṣu Kẹta 2019 ni meji ninu ọmọ igbimọ to gbọ ẹsun to jẹyọ latara idibo naa dajọ pe oludije PDP lo wọle.

Ṣugbọn, o da bi ẹni pe idajọ naa ko ba awọn kan lara mu ni ipinlẹ Ọṣun.

Awọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, Adejare Taofeek

Àkọlé àwòrán, 'Ọṣun kọ idajọ ti wọn fi owo ra.'

Iwọde naa ti ẹgbẹ Osun Concerned Citizens ṣe agbatẹru rẹ waye ni ilu Oṣogbo.

Awọn to n wọde

Oríṣun àwòrán, Adejare Taofeek