Kloe: Èmi kìí mu òògùn olóró, àmọ́ mo fẹ́ràn láti máa wà lẹ́bà omi
Kloe Oluwabusayọ, tii se ara awọn to lọ si BB Naija salaye fun BBC Yoruba pe, ko si ọrọ ifẹ kankan laarin oun ati KB inu BB Naija.
Kloe ni oun ko fẹran ọkunrin to ba ti pupa ju, bikose dudu, pẹlu afikun pe, oun maa n gun ọkada tabi wọ ọkọ ero tẹlẹ, amọ nibayii, ko seese mọ.
O fikun pe, oun kii bikita nipa ohunkohun tẹlẹ, sugbọn ni bayii, oun ti mọ ibiti oun fẹ de nile aye, ti oun si ti n sisẹ tọọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣẹ gbọ́ nípa Alájọ Ṣómólú, tó ta mọ́tò ra kẹ̀kẹ́?
- Yorùbá dùn lédè, ẹ máa sọọ́
- Ẹfunroye Tinubu - Ògbóǹtagí oníṣòwò, olówò ẹrú àti afọbajẹ
- Samuel Ajayi Crowther, òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó gbé èdè Yoruba lárugẹ
- Mọrèmi Àjàṣorò, akọni obìnrin tó gba Ilé Ifẹ̀ sílẹ̀ lóko ẹrú
- Ọwọ́ pálábá ségi fún gbajúgbajà olè méjì tó ń ṣọṣẹ́ lọ́wọ́ l‘Eko
- Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá, Tokyo àti Auxillary ṣèpàdé bòńkẹ́lẹ́
- Ọbasanjọ sọ àsírí sàgbàdèwe rẹ̀
Nigba to n salaye awọn ohun to nifẹ si, Kloe ni oun fẹran lati maa se ounjẹ, oun kii mu oogun oloro, dipo ti oun yoo ba fi mu, yoo dara ki Ọlọrun kuku pe oun sọdọ.
O tẹsiwaju pe, oun fẹran lati maa wa nibi ti omi ba wa, tori omi maa n mu oun roun jinlẹ daada.