Lagos building collapse: LASEMA ní ìwadìí yòó yàtọ̀ lórí ilé tó wó nítorí ààrẹ àtàwọn èèkàn ti gbọ́ sí ìsẹ̀lẹ̀ náà

Ijọba ipinlẹ Eko ti ni iwadii yoo bẹrẹ laipẹ lati mọ ẹni to lẹbi gan lori iṣẹlẹ ijamba ile to wo ni agbegbe Ita faaji nilu Eko.

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA ṣalaye fawọn oniroyin nibi ipade iroyin kan lowurọ ọjọbọ pe iwadii yoo waye lati mọ awọn ohun to ṣokunkun ati awọn ohun to ku diẹ kaato ṣaaju ijamba ile wiwo naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba ti akọroyin ileeṣẹ BBC to wa nibi ibanisọrọ naa beere boya iyatọ yoo wa lori iwadii ọtẹ yii nitori ọpọ ile lo ti wo ṣaaju ti ijọba ṣe iwadii si ni araalu ko ri abalọ-ababọ rẹ, Ọga agba LASEMA naa ni iyatọ yoo wa lọtẹ yii nitori awọn eekan ilu titi kan aarẹ Buhari ti wọn ti gbọ sii.

Ọga agba ajọ LASEMA,Tiamiyu ṣalaye pe ko si ẹni tii le sọ ni pato iye awọn ọmọ ileewe to fara kaaṣa ninu iṣẹlẹ naa nitori pe titi di asiko yii, ẹni to ni ileewe naa ṣi wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nileewosan bayii, ko si si ẹni ti o lee ṣalaye ni pato iye awọn ọmọ ileewe to wa si ileewe ni ọjọru ti iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ.

Bakan naa ni ọga agba LASEMA naa tun ṣalaye pe ajọ naa ko tii lee sọ iye awọn to fara kaaṣa naa lapapọ ṣugbọn ireti wa pe orukọ awọn to wa ninu iṣẹlẹ naa yoo jade laipẹ.

O wa rọ awọn obi tabi alagbatọ to ṣi n wa ọmọ wọn lati tẹ siwaju lọ sawọn ileewosan ti wọn ko wọn lọ fun ayẹwo eeyan wọn.

O ni Ọjọbọ ni wọn yoo pari eto idoola ẹmi to n waye ni ibudo iṣẹlẹ naa.