You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Atiku: N36m ni àwọn kan ń tọrọ fún mi láì mọ̀ lórí ayélujára
Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ti kede faraye pe oun ko mọwọ tabi mẹsẹ ninu ikede agbe sise ti awọn eeyan kan n se fun oun lori itakun agbaye.
Atiku ni agbe ti wọn tẹ pẹpẹ rẹ naa ni wọn sọ pe o wa lati se atilẹyin fun oun lori ẹjọ ti oun pe lati tako esi ibo aarẹ, ti Muahammadu Buhari bori.
Nigba to n fesi si ọrọ yii, ọgbẹni Phrank Shaibu tii se agbẹnusọ fun Atiku lori eto ibaraẹnisọrọ ati aabo ni ko si ohunkohun to kan Atiku ninu bara ori itakun agbaye naa, eyi to ti n fa ariyanjiyan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
"Afojusun ati oju inu ẹni to se agbatẹru eto ẹdawo naa ni eyi jẹ, eto adani rẹ si ni pẹlu, tori, Atiku ko mọ nipa rẹ rara."
Bakan naa ni Shaibu salaye siwaju si pe, owo to to ẹgbẹrun lọna ọgọrun dọla, eyi tii se miliọnu mẹrindinlogoji naira, ni awọn eeyan ọhun kede pe awọn fẹ kojọ fun Atiku lati fi se ẹjọ to pe lori esi ibo aarẹ, to si jẹ pe ni ọjọ kansoso pere, wọn ti ri owo to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira.
Bi o tilẹ jẹ pe wọn ti pa ikede ọhun rẹ lori oju opo ikansira ẹni Twitter ti wọn gbe si, sibẹ agbẹnusọ fun oludije ẹgbẹ APC naa wa n kesi awọn araalu lati takete si ẹdawo ọhun nitori kii se eyi ti Abubakar Atiku lọwọ si.