Nigeria Elections 2019: IPMAN kéde àdínkù ìyè owó epo bẹntiróòlù

Ẹgbẹ alagbata epo aladani lorileede Naijiria IPMAN ti paṣẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ wọn jakejado Naijiria mu adinku ba iye owo epo bẹntiro lati mu irọrun ba awọn eeyan lasiko idibo.

Adinku ti wọn kede ọhun ni lati naira márùndínláàdọ́jọ (N145) lita kan si naira méjìlélógóje N142 tabi ogóje naira N140

Aarẹ ẹgbẹ naa Chindeu Okoronwo to ba ikọ BBC Pidgin sọrọ sọ pe onagba lati mu idagbasoke ba Naijiria ni awọn fi ṣe bẹẹ.

"Ohun ta gbero ni lati mu idẹkun ba awọn ọmọ Naijiria paapa jullasiko idibo yii. Ọna lati ṣe koriya fun awọn oludibo ni nitori pe ti eeyan ba jade lati dibo,ojuṣe rẹ pataki ni o ti ṣe yẹn.''

O ṣafikun pe adinku naa yoo bẹrẹ lati ọjọ Aje ti ṣe ọjọ kejidinlogun Oṣu keji titi di ọjọ kejila Oṣu kẹta ọdun 2019.

Ọgbẹni Okoronkwo salaye pe kii ṣe ẹgbẹ oṣelu lo n gbe igbesẹ yi bi kii ṣe ẹgbẹ IPMAN.

"Ẹ ma jẹ ki a sọrọ nipa owo ti a o padanu.Alafia ti yoo mu ba ilu ni ki ẹ jẹ ki a sọ.A ko le ko iye owo kankan le nini alafia nilu''

Ko ti daju bi ikede yi yoo ti ṣe lapa lara owo irina amọ awọn eeyan n reti ki awọn awakọ din owo irina ọkọ ku nigba ti wọn ko nira epo to iye ti wọn n ra tẹlẹ.

Ajọ eleto idibo Naijiria kede isunsiwajuiboAarẹ ati tawnile asofin orileede Naijiria lati ọjọ kẹrindinlogun Oṣu keji si ọjọ kẹtalelogun Oṣu keji ti idibo Gomina to yẹ ki o waye lọjọ keji Oṣu kẹta ti sun si ọjọ kẹsan Oṣu kẹta .