You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nigeria 2019 Elections: Canada yá, àti àwọn ọ̀nà mì t'ọmọ Nàìjíríá fi bínú sí sísún ìdìbò
Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo fẹ ẹ lọ mu ile si orilẹede Canada lẹyin ti eto idibo aarẹ ati ti ile aṣofin agba ko waye mọ.
Lootọ ni ko fojuhan ẹni to bẹrẹ ipolongo Canada ọhun, amọ ohun ni ijiroro to gbajumọ loju opo Twitter lẹyin ti ajọ INEC kede pe eto idibo ko ni le waye mọ.
Awọn ọmọ Naijiria ọhun to n fi ibinu wọn han n sọ pe, niwọn igba ti ajọ INEC ti jawọn kulẹ, awọn yoo fi Naijiria silẹ lọ si Canada.
Amọ ṣaa, yẹyẹ ni ọpọ fi ọrọ naa ṣe.
Diẹ lara awọn ipolongo Canada ọhun re:
Ọkan lara wọn @PaultwinOkoye fi aworan ọpọlọpọ baalu to n fo lẹẹkan naa han.
Ẹlomii, @laffbro ni tiẹ fi aworan ọkọ moluẹ ti wọn n lo ni ipinlẹ Eko pẹlu ọpọ eniyan to fẹ ẹ wọ inu rẹ lẹẹkan naa.
O ni ''nigba ti awọn ọmọ Naijiria gbọ pe igba Naira ni ọkọ ti yoo gbe wọn de orilẹede Canada.''
Bakan naa ni @YoungSaeed ko gbẹyin. O lo aworan awọn eero nibudo kan lati sọ pe awọn ọmọ Naijiria n sa lọ si Canada.