ASUU Strike: Ìpàdé láàárín ẹgbẹ́ olùkọ́ fásitì àti ìjọba jásí pàbó!

Ipade to waye laaarin ijọba apapọ ati awọn adari ẹgbẹ awọn oluko fasiti ASUU ti fori sanpọn.

Asoju ijọba ati ẹgbẹ ASUU to ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade naa sọ wi pe wọn ti sun ipade si waju di Ọjọ Keje, Osu Keji, ọdun 2019.

Ijọba apapọ ni awọn ko ni aadọta miliọnu naira ti awọn fẹ san bayii, amọ aarẹ ẹgbẹ ASUU ni awọn yoo lọ ba awọn eniyan awọn sọrọ ṣaaju ọjọ ti wọn sun ipade si.

Ipade kẹsan niyii ti ẹgbẹ olukọ fasiti ASUU n se pẹlu Minisita fun ọrọ osisẹ ati igbanisisẹ, Chris Ngige lati bii oṣu mẹta.

Lati Ọjọ Kẹrin, Osu Kọkanla, ọdun 2018 ni awọn oṣisẹ fasiti naa ti bẹrẹ iyansẹlodi lori iwa aibikita si ipo ti ile ẹkọ giga wa lorilẹede Naijiria, ti wọn si n bere fun ki ijọba tun awọn ile ẹkọ giga ṣe pẹlu awọn ohun eto ẹkọ ti igbalode.