You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Presidential Debate:Atiku yọjú, ó kọ̀ láti kópa
ìjíròrò laarin awọn oludije ipo Aarẹ orileede Naijiria ti n waye lolu ilu Naijiria Abuja.
Ṣugbọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar kọ lati kopa nibẹ botilẹ jẹ pe o yọju si gbọgan eto naa.
Alaye to ṣe ni wi pe ohun ko le kopa nitori Aarẹ Muhammadu Buhari ko lati yọju.
O fi ikede idi ti ko fi kopa yi soju opo Twitter rẹ
Atiku ti o kọwọrin pẹlu Aarẹ ile asofin Naijiria Bukola Saraki ṣẹṣẹ dari lati ilẹ Amerika lọjọ abamẹta ni o si sọ wi pe ''Ko tọ ki a ma fa ori lẹyin olori.Ijiroro ta wa ṣe a wa ṣe pẹlu ẹni ti o wa ni ijọba ni''
Atiku wa ta aarẹ Buhari laya lati pade ohun to ba to bẹ fun ijiroro.
Lara awọn to yọju la ti ri Oby Ezekwesili ti ẹgbẹ ACPN,Fela Dutoye ẹgbẹ Alliance for New Nigeria ANN ati Kingsley Moghalu ti ẹgbẹ Young Progressives Party
Ki wa ni awọn to wa n sọ
Fela Durotoye:
Awọn eeyan ko san owo ori ti Naijiria nitori wi pe wọn ko ri anfaani kankan lati owo ori ti wọn n san.
Ohun ti ijọba wa yoo ṣe ni lati ri wi pe a mu adinku ba iye owo ti a n naa gẹgẹ bi ijọba
Ọkọ akero ni maa ma lọ gẹgẹ bi Aarẹ.Mi o lo ọkọ pupọ.
Kingsley Moghalu:
Ijọba mi yoo mu idagbasoke ba awọn igberiko latara pipese imọ ẹrọ ICT ati ohun amayederun paapa julọ fun awọn ọdọ.
A o ṣe ijọba ajumọṣe laarin ọlọdani ati ijọba.
Awa ko niṣe ijọ́ba
Oby Ezekwesili:Ko ya mi lẹnu wipe Atiku ati Buhari ko yọju.
Wọn fi aiyọju wọn kede pe awọ́n ti dagbere fun awa ra ilu.
Bi wọn ba bikita ara ilu ni,wọn yoo yọju.
Asiko lo de bayi fun awọn ara ilu lati yan ijọba tuntun ni Naijiria
Fela Durotoye
Igberaga ni o n saaju iparun.
Bi awọn olori to wa ni ijọba ko ti ṣe yọju fi han wi pe wọn ko mu awọn ara ilu nipataki
Asiko to lati gba ominira lọwọ awọn olori ti ko kun oju osuwọn.