2019 elections: Saraki, Dogara ṣèkìlọ̀ lórí ewu ìbò rírà fún ìdìbò ọ́dún 2019

Awọn aṣofin apapọ orilẹede Naijiria ti pariwo sita pe ibo tita ati rira jẹ penija kan ti yoo koju aṣeyọri eto idibo apapọ lọdun 2019.

Nibi ipade itagbangba kan to waye lori gbigbogun ti ipenija ibo tita ati rira ni ilu Abuja lawọn aṣofin apapọ ti sọrọ yii.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ibo rira ati tita farahan gẹgẹ bii ipenija tuntun ti awọn alakoso eto idibo lorilẹede Naijiria gbọdọ mojuto pẹlu bi o ṣe wọpọ lasiko idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ekiti ati Ọṣun.

Olori ile aṣojuṣofin, Yakubu Dogara ni ohun kan to lee mu ki eto idibo o jẹ itẹwọgba labẹ ilana iṣejọba awarawa naa ni ki irufẹ eto idibo bẹẹ o lọ lai si wahala, ki o wa lai labawọn, ki o si duro lori ifẹ awọn oludibo.

"Ipenija isisinyi ni ibo rira ti o si bani ninu jẹ gidigidi. Gẹgẹ bii ọmọ orilẹede yii, a ko ni lati sọ ara wa di ọdaran, nitori iwa ibo rira tabi tita atawọn iwa aitọ miran lasiko idibo ti da wahala silẹ si ọrun awọn ọmọ orilẹede yii nitori ibẹru bojo lọrọ naa da si aya wọn dipo ki o fun wọn ni igboya lati koju awọn iwa aitọ leto idibo wa."

Ninu ọrọ tirẹ, aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Bukọla Saraki ni gẹgẹ bii ipenija kan ti o n ba eto idibo lorilẹede Naijiria finra, awọn alẹnulọrọ atawọn alaṣẹ gbọdọ dide gbogun tii ni wara-n-ṣeṣa ki o to bọ aṣọ iyi ati ẹyẹ lara eto idibo apapọ ọdun 2019.

"Gbogbo awọn ti ọrọ idibo lorilẹede yii kangbọdọ fihan pe eto idibo ti ko lẹja-n-bakan ninu san ju ẹni to bori idibo lọ.

Ko ni dara ki a maa fi apẹẹrẹ ti ko dara ṣọwọ si awujọ agbaye nipa ailakiyesi ati aikọbiara wa. Gbogbo agbaye gbọdọ rii pe a ṣetan lati gbe igbesẹ itẹsi."