You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé asòfin àpàpọ̀: Owó osù amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ aṣòfin kan dín ní ₦150k sí ₦250k
Laipẹ yii ni awọn amugbalẹgbẹ fun awọn aṣofin agba lorilẹede Naijiria fi ẹhonu han, ti wọn si ṣe iwọde pe awọn aṣofin naa ko san owo oṣu ati ajẹmọnu fun awọn.
Igba akọkọ si kọ niyii ti awọn amugbalẹgbẹ f'awọn aṣofin apapọ to wa niṣakoso lọwọlọwọ, yoo fẹhonu han lori airowo oṣu gba.
Awọn aṣofin naa ti sọrọ pe, awọn ko mọ nkankan nipa rẹ, nitori pe igbimọ to wa fun amojuto ile aṣofin mejeeji lo wa nidi owo oṣu sisan.
Amọ alaye yii ko da awọn amugbalẹgbẹ naa duro lati fi ẹsun kàn pe, aarẹ ile aṣofin agba, abẹnugan ile aṣofin kekere, atawọn mi n dari owó awọn gba ibomi i lọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ má bẹ̀rù àgbára ìjọba àpapọ̀, ànàbolẹ̀ ni PDP yoo nà APC - Saraki
- Ohùn ìjálá lásán ni mo fi ń pa ẹran nínú igbó - Ọdẹ Oníjàálá
- Mo fẹ́ ọkọ mi torí bó se ń kọrin, kìí se torí owó - Ìyàwó Aràrá
- Mo fẹ́ kí àyẹyẹ ìgbeyàwó mi dùn ni mo se bú sẹ́kún - Ọkọ ìyàwó ẹlẹ́kún
- Samuel Ladoke Akintọla jẹ́ Agbẹjọ́rò àti Akọ̀ròyìn tí ọ̀rọ̀ dá lẹ́nu rẹ̀
- Ìgbà tí Aisha Buhari ti f'ọ̀rọ̀ da ìgboro rú lórí ìjọba ọkọ rẹ̀
Awọn amugbalẹgbẹ naa si kọwe ẹbẹ si ajọ EFCC, ICPC, to fi mọ Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ.
Awọn amugbalẹgbẹ naa ni awọn akọsilẹ kan fihan pe, iye awọn jẹ ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹta le aadọrin niye.
Bakan naa ni iwadi fihan wi pe, ẹnikọọkan awọn amugbalẹgbẹ ọhun n gba owo oṣu ti apapọ rẹ n bẹ laarin ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira ( ₦150,000) si ẹgbẹrun lọna ọtalerugba o din mẹwa naira (₦250,000).
Koda, awọn kan tun wa ti owo wọn ju bẹ ẹ lọ. Eyi nii ṣe pẹlu ipele tabi ipo ti iru amugbalẹgbẹ bẹ ẹ ba wa.
Ofin ile aṣofin naa faaye gba aṣofin kọọkan lati ni amugbalẹgbẹ maarun, nigba ti aarẹ ile aṣofin agba lanfaani si amugbalẹgbẹ marundinlaadọta.
Bakan naa ni igbakeji rẹ ni anfaani si ọgbọn, ti awọn olóyè ile si ni anfaani si ogún ẹnikọọkan wọn.
Bakan naa ni ọrọ ri lọdọ awọn ọmọ ile aṣofin kekere.
Abẹnugan ile ni ẹtọ si amugbalẹgbẹ marundinlogoji, igbakeji rẹ, mẹẹdogun, ti ọkọọkan awọn olóyè ile si lẹtọ si mẹwa.
Gbogbo awọn amugbalẹgbẹ yii ni apapọ wọn ko din ni ẹgbẹrun meji le ni ẹẹdẹgbẹta. Gbogbo wọn lo si n gba owo oṣu latinu apo aṣuwọn ile aṣofin.
Apapọ awọn ọmọ ile aṣofin apapọ jẹ irinwo ati mọkandinlaadọrin. Awọn sẹnetọ mọkandinlaadọrin, ati ọtalelọọdunrun aṣoju-ṣofin.
Akojọpọ owo oṣu wọn niyii ti ọkọọkan wọn ba n gba ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun Naira l'oṣu:
- Amugbalẹgbẹ Sẹnetọ - Amugbalẹgbẹ 700 - 150,000x700=105,000,000
- Asoju-ṣofin - Amugblẹgbẹ - 1870.150,000x1870=280,500,000
- Apapọ owo wọn oṣu - 385,500,000 Naira
- Apapọ l'ọdun - 4,626,000,000bn Naira
Ti ọkọọkan awọn amugbalẹgbẹ naa ba n gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ (₦150,000) Naira l'oṣu, apapọ owo wọn yoo jẹ biliọnu mẹrin ati miliọnu lọna okoolelẹgbẹta ati mẹfa Naira (₦4,626,000,000bn) l'ọdun.