Ibadan: Ìdàrúdàpọ̀ wáyé láàrin ọlọ́jà Yoruba àti Igbo nítorí ipò lọ́jà Ògùnpa

Ede-aiyede bẹ silẹ ni Ọjọbọ ni isọ awọn ti o n ta nnkan iranṣọ ni gbajugbaja Ogunpa ni ilu Ibadan.

Ohun ti o si fa ede-aiyede yii gẹgẹ bi BBC News Yoruba ti ṣe gbọ ko ju ija tani yoo jẹ alaga ọja naa eleyi ti o bẹ silẹ laarin awọn ontaja to jẹ ọmọ ilẹ Yoruba ati awọn to jẹ ẹya Igbo nibẹ.

Ohun ti BBC News Yoruba gbọ ni pe awọn ontaja to wa ni ọja naa to jẹ ẹya Igbo ni wọn sọọ nibi ipade kan ti alaga ẹgbẹ awọn ọlọja ohun elo iranṣọ ni ọja ogunpa pe ni imura silẹ fun ajọdun ẹgbẹ naa ti yoo waye ni opin oṣu yii, pe asiko to fun awọn pẹlu lati jẹ alaga ni ọja naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin ti a gbọ tun tẹsiwaju pe eyi lo bi awọn ọlọja to jẹ ọmọ Yoruba nibẹ ninu ti wọn fi fi aake kọri pe "niwọn igba ti ko si ọmọ Yoruba ti o lee da iru aṣọ bẹẹ ṣoro ni ilu Onitsha ati aba nibiti irufẹ ọja ohun elo iranṣọ bayii wa, ko si nnkan to jọọ ni ilu Ibadan."

Titi pa ni ọja naa wa di nnkan bi agogo kan ọsan ki wọn to ṣi ọja naa ni ọjọbọ.

Ninu ọrọ to ba ikọ BBC News Yoruba sọ, alaga ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Kunle Olowu ṣalaye pe lootọ ni edeaiyede bẹ silẹ laarin ọja naa, ṣugbọn laarin awọn eeyan meji ti wọn jẹ ẹya Yoruba ati Igbo nibẹ ni.

Amọ ohun ti Ọgbẹni olowu kuna lati yannana rẹ ni bi edeaiyede laarin ọlọja meji ṣe mu ki wọn gbe ọja naa tipa di nnkan bi agogo kan si meji ọsan.

"Ede aiyede kan waye lootọ kiiṣe ọrọ ati ṣe olori ni wọn n jaasi ṣugbọn a ti yanju ẹ."

Amọṣa awọn eeyan kan to wa ra ọja ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn fidi rẹ mulẹ fun BBC News Yoruba pe "Ọrọ naa n fẹ amojuto nitori lootọ ni wahala naa waye ṣugbọn gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, koda wọn lọ pin pankẹrẹ laarin ọja lati fi na awọn eeyan nibẹ."

Ọrọ naa tun fẹ ba ibo miran yọ nigba ti awọn ọmọ ita ati janduku kan ti ọpọ mọ si awon omo oju ina tun ya bo ọja naa ni nnkan bi agogo mẹrin si marun ti wọn si paṣẹ fun gbogbo awọn ontaja to jẹ ẹya igbo nibẹ lati ti ṣọọbu itaja wọn ki wọn si kuro ni ọja naa lẹyẹ-o-ṣọka.