Fashọla sọ pé ìṣàkóso Awolọwọ nìkan ló ṣee fi wé ti Buhari'

Minisita fun akanṣe iṣẹ, ina ọba, ati ilegbee, Babatunde Raji Faṣọla sọ pe ẹkun Iwọ oorun Guusu ni yoo gba ipo aarẹ lẹyin saa keji Buhari.
Fasọla sọ ọrọ naa nibi ipade apero ita gbangba kan to waye ni gbọngan Emeritus Professor Theophilus Ogunlesi, to wa ni adojukọ ileewosan UCH, ilu Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Afojusun ipade naa jẹ ọna lati mu idagbasoke ati atunṣe ba oju ọna irin, oju ọna ọkọ, awọn ileesẹ nlanla, ina ọba ati bẹẹbẹ lọ,
Lara awọn to kopa nibi ipade naa ni Minisita fun eto iroyin ati asa, Lai Mohammed ati akẹgbẹ rẹ, minisita fun akanṣe iṣẹ, ina ọba, ati ilegbee, Babatunde Raji Faṣọla, ati minisita fun irinna, Rotimi Amaechi, Minisita fun nkan alumọni inu omi, Suleiman Adamu, ati gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ati awọn mi i.

Bakan naa ni awọn ọba alaye, oniṣẹ ọwọ, ẹgbẹ awọn ọlọja, ati awọn to wa ni iṣakoso ninu ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ipade apero naa ni wọn ni yoo fi aaye gba awọn aṣoju ijọba apapọ lati ṣalaye awọn eto ati ilana ti ijọba n gba ṣiṣẹ, ati lati gbọ erongba awọn araalu lori idagbasoke awọn nkan amayedẹrun.
Faṣọla sọ pe ki awọn eniyan ẹkun Iwọ oorun Gusu ṣe atilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari ninu eto idibo ọdun 2019.
O ni iṣakoso kan to o ṣe fi we ti aarẹ Buhari taa ba ni ka sọ nipa minu adehun ipolongo ibo ṣẹ, ni ti Ọbafẹmi Awolọwọ.
O sọ pe awọn ijọba to ti kọja ṣakoso orilẹede Naijiria fun ọdun mẹrindinlogun, wọn si fi ipo naa silẹ lai ni aṣeyọri kankan to pojuowo, ayafi awọn ileri ti wọn ṣe ki wọn to bọ si ipo.
Nkan mẹta ni ẹgbẹ wa, APC, ṣeleri fun yin; eto aabo, ọrọ aje ati lati gbogun ti iwa ijẹkujẹ. Iyatọ akọkọ to wa laarin wa niyii.
O ni ki awọn ẹya Yoruba dibo fun Buhari lati ṣe saa keji, nitori wi pe Iwọ Oorun Gusu ni yoo gbe ijọba fun lẹyin saa keji rẹ.
"Ẹ maa ti jẹ ki ẹnikẹni gbọ. Wọn ti sọ fun wa pe ẹkun Iwọ oorun Gusu lo kan lati bọ si ipo aarẹ lẹyin saa keji Buhari.
O tumọ si pe nkan kan ti ẹ gbọdọ fi sọkan niyẹn lasiko ti ẹ ba fẹ sibo yan adari yin. Ẹ nilo lati tẹle aarẹ Buhari, ka ma ba a padanu anfaani naa."














