You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Osun Election Results 2018: oníkaluku fi èrò rẹ̀ hàn lórí ayélujára
Ìdìbò Ọṣun di àpèrò àwọn olóṣèlù
Ọjọgbọn Afuwape to ṣe alakoso eto idibo to waye lọjọ kejilelogun, oṣu kẹsa an kaakiri ipinlẹ Ọṣun lo kede pe atundi ìbò yoo waye ni ki INEC to le kede ẹni to ba wọle gẹgẹ bii gomina tuntun ti yoo rọpo Ogbẹni Arẹgbẹṣọla.
O ni ibo ti wọn wọgile jẹ 3, 498 nigba tio iyatọ ìbò APC ati PDP to gbegba oroke jẹ 353Link.
Oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Adegboyega Oyetọla ni asiko ọ̀rọ̀ kòí tó fun òun nigba ti BBC kan sii ni Ọṣogbo.
Bakan naa ni Iyola Omiṣore ko tii ba BBc sọrọ ṣugbọn awọn agbẹnusọ rẹ ni àwọn ti n ṣe ipade lori ohun tó kàn lati ṣe.
Ikede Atundi ìbò yii lo ti n bi Ìgè ati Àdùbí kaakiri ayelujara bayii. Ṣaaju ki wọn to kede ni àwọn kan ti gba pe ikede naa ṣeeṣe ko ni ọwọ kan ninu.
Loju Al-Gombawi, ka ni APC lo wọle, INEC yoo ti tete kede ẹni to jawe olubori.
Awọn ẹgbẹ oṣelu PDP ni àwọn ti pariwo sita tẹlẹ ki ọrọ ma le di ohun to di yii nitori pe ati okeere ni oloju jinjin àwọn ti n kigbe.
Bẹẹ, ero ọkan Davido ni pe àwọn ènìyan Ọṣun ti yan ololufẹ wọn fun igba ọtun sipo pẹlu abajade esi ti INEC fi sita lai nilo atundi ibo rara.
Ọpọlọpọ ló gbàgbọ́ pé afurasi ọkunrin ti wọn mu pe o fa èsì ìdìbò Ayedaade ya lo ṣokunfa atundi yii. PDP fi léde ní ìkanni twitter wọn pé
Loju àwọn mii, ohun ti INEc ṣe dára, àṣiṣe ni ki ẹgbẹ PDP gbagbọ pe àwọn ti bori ìbò Ọṣun. Ọgbẹni Ayọ ni:
Loju Oloye Lai Mohammed to jẹ minista fun ifitonileti ati àṣa ni Naijiria, to tun jẹ eekan lẹgbẹ oṣelu APC APC fojú di PDP ni èsì ìdìbò ṣe wọ́ l’Ọsun àràbà APC gbọdọ lọ tun ara mú ni.
Àwọn mii da ẹ̀bi náà ru Ọgbẹni Arẹgbeṣọla pe àìsan owó oṣù lo jẹ ki àwọn ara Ọṣun dibo bẹ́ẹ̀. Tunde lori ikanni rẹ ni @gbosa ni:
Ọpọ gba pé ẹ̀kọ́ nla nidibo Ọṣun yii jẹ fún àwọn èèyàn Naijiria, eyi to fihan pe, idagbasoke ti n ba ètò ìdìbò wa. Amos Cole ni @amosiano ni
Ohun to kọju si ẹnikan kọ ẹyin si ẹlomii bi ìlù gángan, awọn miran gbagbọ pe èsi yii fi òótọ́ inú Buhari hàn pé ọwọ PDP kò mọ́. Amedo lori @amedoreports ni
Ohun to wa ninu iwe ofin Naijiria ni pé, ẹni to ba jawe olubori ninu idibo gbọdọ ni ida kan ninu mẹrin ninu ibo naa ati ida meji ninu mẹta apapọ ijọba ibilẹ ti wọn ti dibo na ninu ipinlẹ, iyẹn, ó kere tán.
Awọn mii gba pe èsì yii fihan pe kò si ẹni ti wọn kò le bori ninu idibo. Omowe Chima ni @amadichima pe akiyesi aarẹ Buhari si koko yii
INEC ni idibo mii yoo wa ni ibudo idibo meje ti wọn wọgile ibo wọn laarin àwọn oludije mejeeji to sunmọ ara wọn julọ.