Omiyalé Àkútè: N50 si N100 làwọn èèyàn fi ń kọjá lórí ẹ̀kún omi
Awọn olugbe agbegbe Akute nipinlẹ Ogun ni oju wọn n ri mabo lọwọ isẹlẹ ẹkun omi to n da wọn laamu.
Awọn olugbe Akute ni, lati igba ti ọwọ ojo ọdun yii ti n le, ni oloko ko ti lee roko mọ, tawọn ko si lee sun tabi wo nitori isẹlẹ ẹkun omi.
Lasiko ti BBC Yoruba kan si adugbo naa, a ri pe aloku ẹrọ amu omi di yinyin, taa mọ si ‘Fridge’, ti ko sisẹ mọ, ati ọpọn iwẹ, taa mọ si ‘Bath Tub’, to ti bajẹ́, lawọn kan n lo lati gbe awọn eeyan kọja lori agbara omiyale naa.
Iwadi BBC Yoruba fi han pe, aadọta naira si ọgọrun naira ni ẹni kọọkan n na lati fi wọ ọkọ oju omi igbalode naa.
Awọn olugbe Akute wa n rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ogun lati tete bawọn wa nkan se si isẹlẹ ẹkun omi naa, eyi to ti n di isẹlẹ ọdọọdun bayii.