Yakubu Dogara tẹ́wọ́ gba fọ́ọ̀mù láti dupò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Ẹgbẹ òṣèlú APC ti fèsì sí ìròyìn tó n já ranyin pe olórí ilé aṣojú ṣofin àgbà Yakubu Dogara tí dára pọ mọ ẹgbẹ òṣèlú PDP.
Egbe náà ni 'Ìgbésẹ rẹ ko jẹ iyalẹnu fún àwọn.'
Nínú atẹjade kàn ti akowe ìpolongo ẹgbẹ APC Yekini Nabena fi ṣòwò sí àwọn akoroyin,APC ni wọlé wode Yakubu Dogara pẹlú PDP ti wa fojú hàn gbangba báyìí.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Nabena ni Dogara kò ''ṣèṣe bẹrẹ ìrìn kurukere pẹlú PDP.''
Bakanna lo ni ní ìgbésẹ ti awọn ti n reti ti pẹ ni ati wi pe kò tú irun kánkan lára àwọn.
O tun tẹsiwaju pe ẹgbẹ awon gba Dogara ni imoran pe ki o ya tete du ipo rẹ labe asia ẹgbẹ tuntun to yan ni nitori pe ijakulẹ nla n duro de.

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Dogara ko ti sọ boya looto loun fi ẹgbẹ APC silẹ tabi ko ri bẹẹ.
Iroyin oloṣelu kan n fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miiran lo n gbode bayii.

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Atiku, Saraki, Akpabio, Tanbuwal, Ortom, koda akọwe ẹgbẹ oṣelu APC , Bọlaji Abdullahi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nibayii iroyin tun ti n kan ka igboro pe olori ile aṣoju-ṣofin Yakubu Dogara pẹlu ti fẹ darapọ mọ iwe orukọ awọn oloṣelu to ti n fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ.
Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba, ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹede Naijiria ti ko fẹ ka darukọ rẹ ni "lootọ ni Họnọrebu Dogara ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Lalẹ ana lo wa gba fọọmu rẹ ṣugbọn nigba ti ko tii sọrọ ni gbangba lori rẹ awa naa pẹlu ṣi fẹ baa dakẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu."
Gbogbo awọn iwe iroyin orilẹede Naijiria ni wọn gbe iroyin jade pe olori ile aṣoju-ṣofin Yakubu Dogara ti gba fọọmu erongba ati dije sile aṣoju-ṣofin lẹẹkan si lọdun 2019.
Ohun ti awọn iwe iroyin ọhun ni wọn n sọ ọ pe bonkẹlẹ ni olori ile naa lọ gba fọọmu rẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Ọkan lara awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣelu naa to ba BBC Yoruba sọrọ ni lootọ ni eyi ati pe bi nnkan ṣe n lọ bayii omi ti n ṣe bi ẹni gbẹ lẹyin ẹja ẹgbẹ oṣelu APC paapaa nile aṣofin apapọ.
Gbogbo akitiyan BBC Yoruba lati wadi ootọ ọrọ yii lati ọdọ igun Họnọrebu Dogara ni ko tii so eso rere pẹlu bi awọn amugbalẹgbẹ rẹ ṣe n fi bi ọgbọn-bi ọgbọn yẹ ibeere yii.

Oríṣun àwòrán, @YakubDogara
Nibayii ẹgbẹ oṣelu APC ko tii sọ ohunkohun lori iroyin yii; bakan naa ni PDP pẹlu mẹnumọ lori ọrọ naa.
Lootọ, iroyin yiya kuro lẹgbẹ oṣelu APC ko lee jẹ kayefi fun ọpọ onwoye oṣelu lorilẹede Naijiria nitori lati igba ti iṣejọba to wa lode yii ti bẹrẹ ni oniruuru awuyewuye ti bẹrẹ lori bi Dogara ati aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Saraki ṣe de ipo.
Amọṣa nibayii, awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣi dẹ oju silẹ lati mọ ibi ti ọrọ naa yoo jasi.












