You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
#NotTooYoungtoRun: Gbájú-ẹ̀ ni Saraki lò fún wa
Ẹgbẹ ọdọ tó pé ará wọn ni ''Not Too Young to Run Movement'' ti bẹnu àtẹ lù bí Ààrẹ ile aṣòfin àgbà Nàìjíríà Bukola Saraki ti ṣe fi ayẹyẹ wọn kéde pé òun fẹ dupo ààrẹ.
Won ni ọtọ ní nnkán tí àwọn pé Saraki wá ṣé kí o tó ṣadede fi ayẹyẹ àwọn kéde èrò rẹ láti dije ipò Ààrẹ Nàìjíríà.
Lọjọbọ ni ẹgbẹ náà fi ọrọ yí síta lójú òpó Twitter wọn lẹyìn tí fónrán fídíò kan se àfihàn àwọn ọdọ tó n dunu níbi ayẹyẹ wọn ti Saraki ti kéde pé òun yóò dije ipò Ààrẹ Nàìjíríà
Ninu atejade naa, ẹgbẹ náà ni ojú gbà awon tí fún Saraki pẹlú bí ọ ti ṣe wù iru wa bẹẹ.
Bakan naa ni wọn tẹsíwájú pé àwọn kò gbé lẹyìn Saraki tàbí ni ero lati kopa gẹgẹ bi ẹgbẹ oselu.
Ọrọ kò rí bẹẹ
Nínú èsì rẹ sí ọrọ àwọn ẹgbẹ ọdọ náà,Senator Bukola Saraki ti agbẹnusọ rẹ Yusuph Olaniyonu fi atẹjade síta lórúkọ rẹ sọ pé òun ṣe ìkéde náà láti ṣe ìwúrí fún àwọn ọdọ ẹgbẹ òṣèlú PDP ton n gbero láti du ipò ní.
''Lootọ ni pé àwọn ọdọ ẹgbẹ náà kò mọ sí èrò mí ṣùgbọ́n mi o gbèrò láti ṣe àkóbá fún wọn.
O ni ''mo mọ riri ipa ti awọn ọdọ nkọ lorílè-èdè yí, má sì má tẹsiwaju láti má b'awọn ṣíṣe pọ''