Èrò ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lóri ohun to ṣẹlẹ̀ si Saraki lojude Ọba

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lọjọ keji ọdun ileya ni ojude Ọba maa n waye lọdọọdun ni Ijẹbu-òde nipinlẹ Ogun.

Aarẹ ile igbimo aṣofin agba l'Abuja, Bukola Saraki ni alejo pataki fun ọdun naa ni ọdun 2018 ni eyi ti àwọn kan tabuku lasiko to n sọrọ.

Awọn eniyan ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi ati iṣesi awọn ololufẹ ẹgbẹ oselu APC lasiko ayẹyẹ ọdun Ojude Ọba ni ilu Ijẹbu Ode.

Awùjalẹ̀ ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú, Ọba Sikiru Adetọna lo kọkọ bu ẹnu atẹ lu bi awọn eniyan ṣe n pariwo APC! APC! lasiko ti Aarẹ Ile Igbimọ Asofin Agba, Bukola Saraki darapọ mọ ayẹyẹ naa.

Ọba Adetọna fikun un pe ọgọrun ọdun niyi ti awọn ti n se ọdun Ojude Ọba lai fi ti ẹgbẹ oselu kankan se.

O ni ohun to buru jai ni ki ẹgbẹ oselu kan ma a polongo lasiko ọdun ọmọ Yoruba to jẹ ọdun Ojude Ọba.

Awọn eniyan ni oju opo ikansiraẹni Twitter naa fi aidunnu wọn han si bi awọn eniyan se sọ gbagede Ojude Ọba di ibi ti wọn ti n se ipolongo ẹgbẹ oselu.

Iroyin fi lede wi pe ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu APC to wa ni ibi ayẹyẹ Ojude Ọba naa mu igbalẹ dani ti wọn si bẹrẹ si ni pe Bukola Saraki ni ole.

Ọkan lara awọn ọmọ Ijebu to wa nibi isẹlẹ naa, sọ wi pe oun ko ni kopa ninu ọdun Ojude Ọba mọ nitori isẹlẹ naa, lẹyin ọgbọn ọdun ti ohun ti n wa si ibi ayẹyẹ naa.