CAN: Ìjọ tó bá bá àwọn èèyàn láramu ni kí wọ́n lọ̀

Ni ẹnu lọọ-lọọ yii, ariwo gee ti gba ori ikanni ayelujara lori bi awọn iranṣẹ Ọlọrun kan ṣe n pe fun 'eso owo' lati ọdọ awọn ọmọ ijọ wọn.

Ariwo iranṣẹ Ọlọrun kan lo kọkọ gba ori afẹfẹ kan, ninu fidio kan ti o ti npe fun awọn ọmọ ijọ ti yoo fi owo dọla ilẹ Amẹrika silẹ, gẹgẹ bii eso fun Ọlọrun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lati ilẹ yii titi de oke okun ni ariwo ti lori isẹlẹ yii - bi awọn kan ṣe n ti wọn lẹyin pe ko si ohun to buru ninu rẹ, ni ọgọọrọ miran ti n pariwo pe Ọlọrun ko roro to bẹẹ.

Eruku ọrọ naa ko ti lọ silẹ, ti fidio kan tun jade bayii ninu eyi ti iranṣẹ Ọlọrun miran, ti n beere fun ilaji miliọnu kan naira lọwọ awọn akẹkọ gẹgẹ bii eso fun Ọlọrun.

eyi lo wa mu kawọn araalu maa beere pe se ilana gbigba eso owo nla-nla yii baa ofin Ọlọrun mu ?

Amọ ṣa, ẹgbẹ CAN ni ọrọ ọhun ku sọwọ awọn eeyan to ba n lọ sawọn ile ijọsin kọọkan. Eyi ti o ba wu wọn ni wọn lee ṣe gẹgẹ bi o ba ṣe dara ninu ọkan wọn.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, olubadamọran fọrọ iroyin fun aarẹ apapọ ẹgbẹ CAN lorilẹede Naijiria, Ẹni-ọwọ Bayọ Oladeji ṣalaye pe, ko si ni ikawọ CAN lati sọ boya ijọ kan lẹtọ lati beere fun owo lọwọ ọmọ ijọ tabi rara.

"Ijọ ti ẹ ba ti n lọ to ba baa yin lara mu naa ni ki ẹ maa lọ. CAN ko lee sọ pe ẹ gbe owo eleyi kalẹ tabi ki ẹ maa gbe tọhun kalẹ.

Ẹgbẹ CAN ko laṣẹ lati ba ẹnikẹni wi tabi gbee soke. Ajọṣepọ laarin awọn onigbagbọ ati ijọba lo jẹ wa logun."