You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Sokoto bandits: Buhari bá ìpínlẹ̀ Sokoto kẹ́dùn lẹ́yìn tí àwọn agbégbọn f'ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò níbẹ̀
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ba awọn eeyan ipinlẹ Sokoto kẹdun lẹyin ti awọn agbebọn ṣekupa ọpọ eeyan ni ijọba ibilẹ Sabon Birni ni pinlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu fi lede ni aarẹ Buhari ti gbadura pe ki Ọlọrun tu awọn ẹbi to padanu awọn eeyan wọn ninu.
Buhari ni o ṣeni laanu pe awọn agbebọn ọhun n gbẹmi awọn eeyan lasiko ti ajakalẹ arun Coronavirus n ba gbogbo aye finra yii.
- Ẹ wo àwọn òfin tí àjọ NCAA gbé jáde fún síṣí pápákọ̀ òfurufú padà ní Nàìjíríà
- Ayálégbé wa tó fi tipá já àbálé mi ṣe àkóbá fún ìgbé ayé mi - Foluke Daramola
- Ènìyàn 182 ni àjọ NCDC kéde pé ó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Covid-19 ní Nàìjíríà
- Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé àwọn alágbara ló ń fi agbára hàn lórí arábìnrin tó fẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kan kọmíṣọ́nà Kogi -Agbẹjọ́rò
Aarẹ ti wa ṣeleri fun awọn ọmọ Naijiria pe ijọba rẹ yoo sa gbogbo akitiyan rẹ lati dabo bo awọn eeyan lọwọ awọn afẹmiṣofo.
Lẹyin naa lo ni awọn ọmọ ogun Naijiria yoo tẹsiwaju lati ma kọju ija si awọn agbebọn ọhun ki alaafi le wa lagbegbe naa atawọn agbegbe mii ti wọn ti n ṣoṣẹ.
Iroyin ni awọn agbebọn ọhun ya bo ijọba ibilẹ naa lẹyin nnkan bii wakati mẹrinlelogun ti gomina ipinlẹ ọhun, Aminu Tambuwal ṣabẹwo sibẹ.
Sokoto: Olùrànlọ́wọ́ 252 kọ̀wé fipò sílẹ̀ nínú ìjọba Tambuwal
Ó kéré tán ààdọ́talénígbà lé méjì olùbádámọ̀ràn àti olùrànlọ́wọ́ fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto Aminu Waziri Tambuwal ló ti kòwé fipò sílẹ̀.
Àwọn òṣìṣẹ́ tó kọ̀wé fipò sílẹ̀ ọhún sàlàyé pé ìgbésẹ̀ àwọn kò ṣẹ̀yìn ìpinu Gómìnà láti fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀, àti pé àwọn ò ṣetán lati fi ẹgbẹ́ oṣèlú APC sílẹ̀ èyí kò sì ni ṣeṣe ṣe lati tẹ̀síwáju bi alábaṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú gómìnà.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Lásìkò tí wọn ń fi ọ̀rọ̀ náà to àwọn oníròyìn léti lọ́jọ́ àìkú ní ìpínlẹ̀ Sokoto àgbẹnusọ fun àwọn olùbádámọ̀ràn Dasuki Haske, sàlàyé pé ìgbéṣẹ̀ àwọn kò sẹ̀yìn ìnú kan tí àwọn fi bá ẹgbẹ́ lò.
'A ń fi gbogbo ẹnu sọọ́ pé a ò lé tẹ̀lé gómìnà Tambuwal ló sí ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun rẹ̀., a ti ṣeán láti dúró si ẹgbẹ́ APC'
Aminu Tambuwal darapo mọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
Lẹyin ti aarẹ ile asofin agba l'Abuja Bukola Saraki fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọ si PDP lọjọ Iṣegun, Gomina Ipinlẹ Sokoto Aminu Tambuwal naa ti kede loju opo Twitter pe, oun ti ba gbẹ oselu PDP lọ.
Tambuwal ni oun fi ọrọ naa lọ ọpọ eeyan nipinlẹ Sokoto, ti wọn si gba pe ki oun to gbe igbesẹ naa.
Ọgọọrọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn pejọ siwaju Ile Ijọba Ipinlẹ Sokoto ni Ọjọru saaju ikede naa.
Ọgọọrọ awọn ololufẹ rẹ ni wọn pejọ siwaju Ile Ijọba Ipinlẹ Sokoto loni Ọjọru saaju ikede naa.
Ẹwẹ, akowe ìpolongo ẹgbẹ́ òṣèlù APC, Bolaji Abdullahi, lokọkọ kọwe fi ipo rẹ silẹ ninu ẹgbẹ oselu naa l'Ọjọru.
Abdullahi ninu atẹjade to fi sita sọ wi pe nitori rogbodiyan to su jade ninu ẹgbẹ oselu naa lo mu oun pinnu lati fi ẹgbẹ oselu APC silẹ.
Ti a ko ba gbagbe, owurọ Ọjọ Isegun ni akowe ẹgbẹ APC tẹlẹri naa ké gbàjarè pé, òtítọ kan kò sí nínú ìròyin kan to ni òún ti kọ̀wé fipò silẹ gẹ́gẹ́ bi ọmọ ẹgbẹ́ APC, láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣẹ́lú People's Democratic Party (PDP).
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:
Abdullahi fìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀, ní ilé ẹgbẹ́ APC l'Abuja wípe ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ ní, kí ẹnikẹ́ni máa ṣe gbàágbọ.
Ó ní àìsí nílé mínísítà fún eré ìdárayá tẹ́lẹ̀ rí, ló dákún àhesọ ọrọ tó gbòde kan, nítorí ìpàdé àwọn ọmọ igbimọ amusẹya ẹgbẹ́ APC kò wáyé l'ọ́jọ́ ajé, èyí sì mú kí ó ma ṣeeṣe láti ṣe ìpàdé lórí bọyá òùn yóò fi ẹgbẹ́ sílẹ̀.
Nígbà tó ń fesì lóri èrò rẹ̀ nípa ààrẹ ilé ìgbimọ̀ aṣofin tó kúrò nínú ẹgbẹ́, o ní èyí kò tọ́ka sí pe, òun yóò fí ẹgbẹ́ APC sílẹ̀.
'' Iwáju ilé ní mo gbà wọlẹ́ sinu APC, tí ń o bá sì lọ, mí ò ní gba ẹ̀yìnkùlé lọ."