Oshiomole: Asaajú, àtẹ̀lé yẹ kó fìmọ̀ sọ̀kan nínú APC

Alaga tuntun fun ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomhole, ti kede pe aisi ifẹnuko to kuna laarin awọn adari ẹgbẹ ati awọn ọmọ ẹgbẹ lo n da wahala silẹ lẹgbẹ oṣelu naa.

Adams Oshiomole ni, oun yoo rii daju pe eto oṣelu tiwantiwa fẹsẹ rinlẹ laarin ẹgbẹ oṣelu naa, eleyii ti yoo fun awọn ọmọ ẹgbẹ lẹnu ọrọ ninu bi nnkan ṣe n lọ si laarin ẹgbẹ oṣelu naa.

Ninu ọrọ to ba awọn akọ̀royin sọ nibi ipade apapọ ẹgbẹ oṣelu APC to n lọ l'Abuja, lẹyin ti wọn ti kede rẹ gẹgẹ bii alaga tuntun fẹgbẹ oṣelu naa, Adams Oshiomole ni, nibi ti ọrọ de duro bayii laarin ẹgbẹ oṣelu APC, ati adari, ati ọmọlẹyin lo gbọdọ lẹnu lori bi idagbasoke yoo ṣe de ba ẹgbẹ oṣelu naa.

Lori dukuu to n waye lawọn ipinlẹ kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa, Oshiomole ni, igbagbọ oun ni pe bi ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ ṣe gbimọ pọ̀ gbe oun wọle, n fun oun ni idaniloju pe afẹfẹ ifẹ yii ni oun yoo gun lati fi wa ojuutu si awọn aawọ naa.

Bakan naa lo tun ni awọn aṣiwaju feto oṣelu ati eto karakata lagbo ẹgbẹ oṣelu APC , yẹ ko jumọ joko pọ lati gbe ilana ọtun kalẹ, eleyii ti yoo ṣe akawe ohun gan to n damu orilẹede yii to bẹẹ gẹẹ, ti awọn ọmọ Naijiria ko ni lee maa fi oju idẹyẹsi ẹsin, ẹya tabi ipo lawujọ, wo ara wọn mọ.