You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
APC Convention: Buhari dúpẹ́ fún ìpàdé àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà
Aarẹ Muhammadu Buhari, ninu ọrọ apilẹkọ to ka nibi ipade apapọ ẹgbẹ oselu rẹ, All Progressive Congress, APC, dupẹ pupọ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa fun aseyọri ipade apapọ fẹgbẹ oselu ọhun, eyi tii se akọkọ iru rẹ lẹyin idibo ọdun 2015.
Buhari tun wa ki awọn asoju to moke nibi ipade abẹle ẹgbẹ APC lati awọn wọọdu ati ipinlẹ ku oriire, ti wọn wa sibi ipade apapọ naa lati yan awọn oloye apapọ ẹgbẹ tuntun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bakan naa lo tun ki awọn olori ẹgbẹ tẹlẹ fun akitiyan wọn lati ri daju pe ẹgbẹ oselu APC moke ninu eto idibo to kọja naa.
"Mo fẹ fi da gbogbo yin loju pe lai naani awọn awuye-wuye kọọkan to suyọ lasiko eto idibo abẹ́nu lawọn wọọdu ati ipinlẹ, sibẹ́, ẹ́gbẹ oselu naa yoo tubọ maa ni okun si ni."
O wa rọ awọn ọmọ ẹ́gbẹ to n fapa janu lati tubọ nigbagbọ ninu ẹgbẹ oselu naa.