World Cup 2018: Saba sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ nípa ìdíje ní Russia

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Wákàtí méjìlá kí ìfẹsẹ̀wónsẹ̀ Naijiria àti Iceland tó wáyé ni arákunrin kan, Tolulope Saba tí ó ń jẹ́ @tolusaba ní Twitter tí kọọ̀ pé Super Eagles yóò borí pẹ̀lú ayò méjì sí òdo.

Nígba tí ìfẹsẹ̀wónsẹ̀ náà parí tí ó sì rí bó ṣe sọ́ ní ó bá d'olókìkí. Ní bí ìṣẹ́jú mélòó kan tí ayò náà parí, àsọtẹ́lẹ̀ náà lórí Twitter ti ní ẹda bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́sàń.

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn tó rí àsọtẹ́lẹ̀ náà.

Àwọn kan tó fèsì sí àsọtẹ́lẹ̀ náà tilẹ̀ ní kó padà sùn kó wá fún àwọn ní nọmba tí àwọm fi lè ta tẹ́tẹ́ kí wọ́n sì jẹ.

Tolulope ni oríṣiríṣi ibéérè tí ọmọ Naijiria ń bééè látàrí àsọtélẹ̀ náà tí wá peléke báyìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: