You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ahmed Musa: Akọ̀royin Saudi Arabia ké gbàjarè torí orúkọ
Orúkọ ló da Ahmed Al Omran àti Ahmed Musa pọ̀. Sùgbọn bí òun ṣe jẹ́ akọ̀ròyin ní Saudi Arabia, pẹ̀lu àpèjẹ́ @Ahmed lórí Twitter, Ahmed Musa jẹ́ agbábọ́ọ́lù Super Eagles tó lókìkí jú lónìí nítorí bó ṣe gbé Naijiria ga pẹ̀lú ayò méji sí òdó pẹ̀lú Iceland.
Bi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Naijira àti Iceland ṣe pari ni àwọn ọmọ Naijiria bẹ̀rẹ̀ sí ní kàn sí @ahmed,tíí se ojú òpó Twitter akọ̀ròyìn tí wọ́n ṣe ròpé oun ni Ahmed Musa.
Ní kía ni akọ̀ròyìn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ ọmọ Naijiria pé, òun kìí ṣe agbabọ́ọ́lù náà. Ìkànni Ahmed Musa gangban ni @Ahmedmusa718.